Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ rí i dájú pé ọba tí Olúwa Ọlọ́run yín yàn fún un yín ní ẹ yàn. Ó gbọdọ̀ jẹ́ láàrín àwọn arákùnrin yín. Ẹ má ṣe fi àjèjì jẹ ọba lórí i yín: àní ẹni tí kì í ṣe arákùnrin ní Israẹli.

  2. Síwájú sí i, ọba náà kò gbọdọ̀ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin jọ fún ara rẹ̀, tàbí kí ó rán àwọn ènìyàn náà padà sí Ejibiti láti wá àwọn ẹṣin sí i, nítorí pé Olúwa ti sọ fún un yín pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ tún padà lọ ní ọ̀nà náà mọ́.”

  3. Èyí yóò sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun ó sì máa kà nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kí ó lè máa kọ́ àti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà rẹ̀ tọkàntọkàn.

  4. Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, àní gbogbo ẹ̀yà Lefi, wọn kì yóò ní ìpín tàbí ogún láàrín Israẹli, wọn yóò máa jẹ nínú ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa, nítorí òun ni ogún un tiwọn.

  5. Wọn kì yóò ní ìní láàrín àwọn arákùnrin wọn; Olúwa ni yóò jẹ́ ìní i tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.

  6. Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n àti àwọn ọmọ wọn láti inú gbogbo ẹ̀yà láti dúró àti láti ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa títí láé.

  7. Tí ọmọ Lefi kan bá sì wá láti ibikíbi nínú àwọn ìlú u yín ní Israẹli, níbi tí ó ń gbé ṣe àtìpó, tí ó sì wá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀ sí ibi tí Olúwa yóò yàn.

  8. Nígbà náà ni ó lè máa ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi arákùnrin rẹ̀ ti ń dúró ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú Olúwa níbẹ̀.

  9. Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ìríra àwọn orílẹ̀-èdè náà tí ó wà níbẹ̀.

  10. Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìríra sí Olúwa, àti nítorí àwọn ìwà ìríra wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde kúrò níwájú rẹ.

  11. O ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

  12. Àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ yóò gba ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé, wọ́n fetí sí tí àwọn tí ó ń ṣe oṣó tàbí ṣe àfọ̀ṣẹ. Ṣùgbọ́n, ní ti ìwọ, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò fi ààyè gbà ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

  13. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé wòlíì kan dìde gẹ́gẹ́ bí èmi láàrín àwọn arákùnrin rẹ. Tìrẹ ni kí o gbọ́.

  14. Nítorí èyí ni ohun tí ìwọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Horebu ní ọjọ́ àjọ, nígbà tí ìwọ wí pé, “Kí àwa má ṣe gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run wa tàbí rí iná ńlá yìí mọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò kú.”

  15. Olúwa sì wí fún mi pé, “Ohun tí wọ́n sọ dára.

  16. Èmi yóò gbé wòlíì kan dìde fún wọn láàrín àwọn arákùnrin wọn bí ìwọ, Èmi yóò fi ọ̀rọ̀ mi sí i ní ẹnu, yóò sì sọ fún wọn gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un.

  17. Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi tí wòlíì náà yóò sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra à mi yóò sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

  18. Ṣùgbọ́n bí wòlíì kan bá kùgbù sọ ọ̀rọ̀ kan tí èmi kò paláṣẹ fún un láti sọ ní orúkọ mi tàbí wòlíì tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ ọlọ́run mìíràn, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ ní láti kú.”

  19. Ṣùgbọ́n ìwọ lè wí ní ọkàn rẹ pé, “Báwo ni àwa yóò ṣe mọ ọ̀rọ̀ tí Olúwa kò sọ?”

  20. Nígbà tí ohun tí wòlíì bá sọ ní orúkọ Olúwa kò bá wá sí ìmúṣẹ tàbí jẹ́ òtítọ́, ìyẹn ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa kò sọ, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ tí sọ láìwádìí. Kí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.

  21. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá ti pa àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò fi ilẹ̀ wọn fún ọ run, àti nígbà tí ìwọ bá ti lé wọn jáde tí o sì dó sí àwọn ilẹ̀ àti ilé wọn gbogbo.

  22. Ìwọ yóò ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara à rẹ láàrín ilẹ̀ rẹ tí Olúwa Ọlọ́run fún ọ láti ni.

  23. Ṣe àwọn ọ̀nà sí wọn àti kí o pín ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún sí ọ̀nà mẹ́ta nítorí kí apànìyàn lè sá níbẹ̀.

  24. Tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì fẹ́ agbègbè rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba ńlá a yín, tí ó sì fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí fún wọn,

  25. nítorí tí ìwọ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo òfin yìí tí mo pàṣẹ fún ọ lónìí yìí, kí o fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì rìn ní ọ̀nà an rẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà, kí o ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀.