Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ wòlíì tàbí àlá náà, Olúwa Ọlọ́run yín ń dán an yín wò ni, láti mọ̀ bóyá ẹ fẹ́ràn rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn an yín.

  2. Olúwa Ọlọ́run yín ni kí ẹ tẹ̀lé, Òun ni kí ẹ bu ọlá fún, ẹ pa òfin rẹ̀ mọ́ kí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, ẹ sìn ín, kí ẹ sì dìímú ṣinṣin.

  3. Wòlíì náà tàbí alálàá náà ni kí ẹ pa, nítorí pé wàásù ìṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú yín jáde láti Ejibiti wá, tí ó sì rà yín padà lóko ẹrú. Ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lójú ọ̀nà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín láti máa rìn. Ẹ gbọdọ̀ yọ ibi náà kúrò láàrín yín.

  4. Sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí pé ó gbìyànjú láti fà ọ́ kúrò lẹ́yìn Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó mú ọ jáde ti Ejibiti wá kúrò ní oko ẹrú.

  5. Bí ẹ̀yin bá gbọ́ tí a sọ nípa èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín láti máa gbé,

  6. Ẹ kó gbogbo ìkógun ìlú náà, sí àárín gbogbo ènìyàn, kí ẹ sun ìlú náà àti gbogbo ìkógun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun sí Olúwa Ọlọ́run rẹ. Ó gbọdọ̀ wà ní píparun láéláé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ tún un kọ.

  7. A kò gbọdọ̀ rí ọ̀kan nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun wọ̀n-ọn-nì lọ́wọ́ yín, kí Olúwa ba à le yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀, yóò sì ṣàánú fún un yín, yóò sì bá a yín kẹ́dùn, yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, bí ó ti fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá yín.

  8. Nítorí pé ẹ̀yin gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ̀yin sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí mo ń fún un yín lónìí yìí, tí ẹ̀yin sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ̀.

  9. Ọmọ Olúwa Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́: nítorí náà, ẹ má ṣe ya ara yín ní abẹ. Ẹ má ṣe gé irun iwájú orí yín nítorí òkú.

  10. Nítorí pé ènìyàn mímọ́ ní ẹ jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run ti yàn yín láti jẹ́ ìṣúra iyebíye rẹ̀.

  11. Ẹ má ṣe jẹ ohun tí ó ti kú sílẹ̀. Ẹ lè fún àwọn àjèjì tí ń gbé ní èyíkéyìí nínú ìlú yín. Òun lè jẹ ẹ́ tàbí kí ẹ tà á fún àwọn àjèjì. Ṣùgbọ́n ènìyàn mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.

  12. Ẹ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àti àkọ́bí àwọn màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín, níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, ní ibi tí yóò yàn bí ibùgbé orúkọ rẹ̀. Kí ẹ lè kọ́ bí a ṣé ń bu ọlá fún Olúwa Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.

  13. Bí ibẹ̀ bá jì tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì ti bùkún fún ọ, tí o kò sì le ru àwọn ìdámẹ́wàá rẹ (nítorí pé ibi tí Olúwa yóò yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí jìnnà jù).

  14. Ẹ pààrọ̀ àwọn ìdámẹ́wàá yín sí owó, ẹ mú owó náà lọ sí ibi tí Olúwa yóò yàn.

  15. Fi owó náà ra ohunkóhun tí o bá fẹ́, màlúù, àgùntàn, wáìnì, tàbí ọtí líle, tàbí ohunkóhun tí o bá fẹ́. Kí ìwọ àti ìdílé rẹ sì jẹ ẹ́ níwájú Olúwa níbẹ̀ kí ẹ sì máa yọ̀.

  16. Kí àwọn Lefi (tí kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn) àti àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé ìlú yín lè wá, kí wọn sì jẹ kí wọn sì yó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ le è bùkún fún ọ, nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

  17. Báyìí ni kí ẹ máa ṣe é. Gbogbo ẹni tí wọ́n jẹ ní gbèsè gbọdọ̀ fojú fo gbèsè tí ó ti yá ará Israẹli ènìyàn rẹ̀. Kò gbọdọ̀ béèrè ohun náà, lọ́dọ̀ ará Israẹli ènìyàn rẹ̀ tàbí lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀: nítorí pé a ti kéde àkókò Olúwa láti fojú fo gbèsè.

  18. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò tọ́ sí nínú yín, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀ nínú ilẹ̀ náà tí ó ń mú un yín lọ láti gbà bí ìní yín.

  19. Kìkì bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín tí ẹ sì kíyèsára láti máa rìn nínú gbogbo àṣẹ wọ̀nyí, tí èmi ń pa fún un yín lónìí.

  20. Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín bí ó ti ṣèlérí, ẹ̀yin yóò sì máa yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ẹ kì yóò sì tọrọ. Ẹ ó ṣàkóso ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò sí orílẹ̀-èdè tí yóò lè jẹ ọba lé e yín lórí.

  21. Bí tálákà kan bá wà láàrín àwọn arákùnrin yín ní èyíkéyìí àwọn ìlú, ilẹ̀ náà tí Olúwa yín yóò fún un yín. Ẹ má ṣe ṣe àìláàánú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe háwọ́ sí arákùnrin yín tí ó jẹ́ tálákà.

  22. Ẹ ṣọ́ra kí èrò búburú kan má ṣe sí nínú àyà rẹ wí pé, “Ọdún keje tí í ṣe ọdún ìyọ̀ǹda gbèsè ti súnmọ́,” nípa bẹ́ẹ̀, ojú rẹ a sì burú sí arákùnrin rẹ tálákà, tí ìwọ kò sì fun ní nǹkan, o kò sì fun ní nǹkan kan. Òun a si kígbe pe Olúwa nítorí rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ.

  23. Fún un tọkàntọkàn, láìsí ìkùnsínú, nítorí èyí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, àti gbogbo ìdáwọ́lé rẹ.

  24. Fi tọkàntọkàn fún un láti inú agbo ewúrẹ́ rẹ, ilẹ̀ ìpakà rẹ, àti ibi ìfúntí rẹ. Fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti bùkún fún ọ tó.

  25. Ẹ rántí pé ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ní Ejibiti, Olúwa Ọlọ́run yín sì rà yín padà, ìdí nìyí tí mo fi pa àṣẹ yìí fún un yín lónìí.