Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní àkókò ìjọba Josiah ọba, Olúwa wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Israẹli aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀.

  2. Mo rò pé nígbà tí wọ́n ti ṣe èyí wọn yóò padà, wọn kò padà, Juda aláìgbàgbọ́ arábìnrin rẹ̀ náà sì rí i.

  3. Mo fún Israẹli aláìnígbàgbọ́ ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, mo sì ké wọn kúrò nítorí gbogbo àgbèrè wọn. Síbẹ̀ mo rí pé Juda tí ó jẹ́ arábìnrin rẹ̀ kò bẹ̀rù, òun náà sì jáde lọ láti lọ ṣe àgbèrè.

  4. Látàrí gbogbo nǹkan wọ̀nyí Juda arábìnrin rẹ̀ aláìgbàgbọ́ kò padà tọ̀ mí wá pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, bí kò ṣe nípa fífarahàn bí olóòtítọ́,” ni Olúwa wí.

  5. Olúwa wí fún mi pé, “Israẹli aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Juda tí ó ní ìgbàgbọ́ lọ.

  6. Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá: “ ‘Yípadà, Israẹli aláìnígbàgbọ́,’ ni Olúwa wí. ‘Ojú mi kì yóò korò sí ọ mọ́, nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni Olúwa wí. Èmi kì yóò sì bínú mọ́ títí láé.

  7. Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ, ìwọ ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ ti wá ojúrere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì lábẹ́ gbogbo igikígi tí ó gbilẹ̀, ẹ̀yin kò gba ohun mi gbọ́,’ ” ni Olúwa wí.

  8. “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni Olúwa wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Sioni.

  9. Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀.

  10. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí, “àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, ‘Àpótí ẹ̀rí Olúwa.’ Kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́.

  11. Ní ìgbà náà, wọn yóò pe Jerusalẹmu ní ìtẹ́ Olúwa gbogbo orílẹ̀-èdè yóò péjọ sí Jerusalẹmu láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ Olúwa, wọn kì yóò sì tún tẹ̀lé àyà líle búburú wọn mọ́.

  12. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Juda yóò darapọ̀ mọ́ ilé Israẹli. Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.

  13. “Èmi fúnra mi sọ wí pé, “ ‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó, kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrin kí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’ Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’ o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn.

  14. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi. Ìwọ ilé Israẹli,” ni Olúwa wí.

  15. A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga, ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po, wọ́n sì ti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn.

  16. “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́, Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.” “Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run wa.

  17. Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrúkèrúdò tí ó wà ní àwọn orí òkè kéékèèké àti àwọn òkè gíga, nítòótọ́, nínú Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà Israẹli wà.

  18. Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa, kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀. A ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, àwa àti àwọn baba wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní a kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”

  19. “Tí ìwọ yóò bá yí padà, ìwọ Israẹli, padà tọ̀ mí wá,” ni Olúwa wí. “Tí ìwọ yóò bá sì mú ìríra rẹ kúrò níwájú mi, ìwọ kí ó sì rìn kiri.

  20. Tí ó bá jẹ́ lóòtítọ́ àti òdodo ni ìwọ búra. Nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láààyè, nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò di alábùkún fún nípasẹ̀ rẹ, àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.”

  21. Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu: “Hú gbogbo ilẹ̀ tí ẹ kò lò rí, kí o má sì ṣe gbìn sáàrín ẹ̀gún.

  22. Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwa, kọ ọkàn rẹ ní ilà, ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná, nítorí ibi tí o ti ṣe kì yóò sí ẹni tí yóò pa á.

  23. Nítorí náà, gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀ káàánú kí o sì pohùnréré ẹkún, nítorí ìbínú ńlá Olúwa kò tí ì kúrò lórí wa.

  24. “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí pé, “Àwọn ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn, àwọn àlùfáà yóò wárìrì, àwọn wòlíì yóò sì fòyà.”

  25. Nígbà náà ni mo sì wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jerusalẹmu jẹ nípa sísọ wí pé, ‘Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà,’ nígbà tí o jẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa.”