Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé; ìwọ ni o ti rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.

  2. Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí; ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

  3. Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ, nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.

  4. Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá.

  5. Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú; ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn, ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.

  6. Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa; mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”

  7. Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi àti àwọn onínúnibíni.

  8. Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára; gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

  9. Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa; nítorí pé mo ké pè ọ́; jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú; jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.

  10. Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó, èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.

  11. Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn; ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu kúrò nínú ìjà ahọ́n.

  12. Olùbùkún ni Olúwa, nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn, nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.

  13. Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi, “A gé mi kúrò ní ojú rẹ!” Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

  14. Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́! Olúwa pa olódodo mọ́, ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

  15. Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.

  16. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

  17. Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára; agbára mi gbẹ tán gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.

  18. Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́. Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,” ìwọ sì dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

  19. Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ ní ìgbà tí a lè rí ọ; nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè, wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.

  20. Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi; ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu; ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

  21. Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.

  22. Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.

  23. Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo; ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.

  24. Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo; ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.

  25. Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù; ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.