Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́, ó ń faradà títí láéláé. Ìdájọ́ Olúwa dájú òdodo ni gbogbo wọn.

  2. Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí; nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.

  3. Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀? Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.

  4. Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá; má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi. Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin, èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

  5. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.

  6. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú; kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.

  7. Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa. Kí Olúwa kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.

  8. Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé, Olúwa pa ẹni àmì òróró rẹ̀ mọ́. Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.

  9. Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin, ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.

  10. Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba! Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!

  11. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ, àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!

  12. Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.

  13. Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un, àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.

  14. Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un; ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.

  15. Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un: ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.

  16. Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa; nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà kì yóò sípò padà.

  17. Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí; ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.

  18. Nígbà tí ìwọ bá yọ ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru. Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀, àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.

  19. Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀, àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.

  20. Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.

  21. Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.

  22. Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ; a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.

  23. Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi. Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀? Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là, àní sí igbe ìkérora mi?

  24. Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn: àti ní òru èmi kò dákẹ́.

  25. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ; ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó.