Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ, èmi ti pa ara mi mọ́ kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà.

  2. Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ; ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀.

  3. Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

  4. Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.

  5. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ; fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,

  6. Dìde, Olúwa, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ.

  7. Olúwa, nípa ọwọ́ rẹ, gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí. Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́; àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn.

  8. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo; nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.

  9. Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé. Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.

  10. Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi. Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.

  11. Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún, a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.

  12. Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa; mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́. Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi; ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.

  13. Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì, ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí; wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.

  14. Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá; iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.

  15. Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá; àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

  16. Ó gun orí kérúbù, ó sì fò; ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.

  17. Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run.

  18. Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná

  19. Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá; Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná.

  20. Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká, ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.

  21. A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn òkun hàn, a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé nípa ìbáwí rẹ, Olúwa, nípa fífún èémí ihò imú rẹ.

  22. Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú; Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.

  23. Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi; ṣùgbọ́n Olúwa ni alátìlẹ́yìn mi.

  24. Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá; Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi.

  25. Olúwa ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi.