Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi! Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,

  2. kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.

  3. A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀; àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

  4. Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú, àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.

  5. Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí; jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.

  6. Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa; jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.

  7. Èéha ti ṣe, Olúwa, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré? Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?

  8. Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀; Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa.

  9. Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀; kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀.

  10. Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo; òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i; òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.

  11. Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé; Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”

  12. Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run. Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.

  13. Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run? Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀, “Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”?

  14. Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora; Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ. Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ; Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.

  15. Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi; pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀ tí a kò le è rí.

  16. Olúwa ń jẹ ọba láé àti láéláé; àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣègbé lórí ilé rẹ.

  17. Ìwọ́ gbọ́, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára; Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,

  18. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa. Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé, “Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.

  19. Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run. Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn; ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.

  20. Olúwa ń yẹ olódodo wò, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.

  21. Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó; àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.

  22. Nítorí, olódodo ní Olúwa, o fẹ́ràn òdodo; ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.

  23. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi. Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́; olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn.

  24. Kí Olúwa kí ó gé ètè èké wọn àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu

  25. “Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní, Èmi yóò dìde nísinsin yìí,” ni Olúwa wí. “Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.”