God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ọba pe Ṣimei lẹ́jọ́, ó wí fún un pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ti mú ọ búra ní ti Olúwa, èmi sì ti kìlọ̀ fún ọ pé, ‘Ní ọjọ́ tí ìwọ bá kúrò láti lọ sí ibikíbi, kí o mọ̀ dájú pé ìwọ yóò kú.’ Nígbà náà ni ìwọ sì sọ fún mi pé, ‘Ohun tí ìwọ sọ dára. Èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn.’
Èéṣe, nígbà náà tí ìwọ kò pa ìbúra Olúwa mọ́, àti kí o sì ṣe ìgbọ́ràn sí àṣẹ tí mo pa fún ọ?”
Ọba sì tún wí fún Ṣimei pé, “Ìwọ mọ̀ ní ọkàn rẹ gbogbo búburú tí ìwọ ti ṣe sí Dafidi baba mi. Báyìí, Olúwa yóò san gbogbo ìṣe búburú rẹ padà fún ọ.
Ṣùgbọ́n a ó sì bùkún fún Solomoni ọba, ìtẹ́ Dafidi yóò sì wà láìfòyà níwájú Olúwa títí láéláé.”
Solomoni sì bá Farao ọba Ejibiti dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó. Ó sì mú un wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹmpili Olúwa, àti odi tí ó yí Jerusalẹmu ká.
Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ènìyàn ṣì ń rú ẹbọ ní ibi gíga, nítorí a kò tí ì kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa títí di ìgbà náà
Solomoni sì fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí Olúwa nípa rírìn gẹ́gẹ́ bí òfin Dafidi baba rẹ̀, àti pé, ó rú ẹbọ, ó sì fi tùràrí jóná ní ibi gíga.
Ní Gibeoni, Olúwa fi ara han Solomoni lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì wí pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí o bá ń fẹ́ kí èmi ó fi fún ọ.”
“Nísinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jẹ ọba ní ipò Dafidi baba mi. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ jíjáde àti wíwọlé mi.
Ìránṣẹ́ rẹ nìyí láàrín àwọn ènìyàn tí o ti yàn, àwọn ènìyàn ńlá, wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò sì lè kà wọ́n tàbí mọye wọn.
Nítorí náà fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti le ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ àti láti mọ ìyàtọ̀ láàrín rere àti búburú. Nítorí ta ni ó lè ṣe àkóso àwọn ènìyàn ńlá rẹ yìí?”
Inú Olúwa sì dùn pé Solomoni béèrè nǹkan yìí.
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ ti béèrè fún èyí, tí kì í ṣe ẹ̀mí gígùn tàbí ọrọ̀ fún ara rẹ, tàbí béèrè fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, ṣùgbọ́n fún òye láti mọ ẹjọ́ dá,
èmi yóò ṣe ohun tí ìwọ ti béèrè. Èmi yóò fún ọ ní ọgbọ́n àti ọkàn ìmòye, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ẹnìkan tí ó dàbí rẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò dìde tí yóò dàbí rẹ lẹ́yìn rẹ.
Síwájú sí i, èmi yóò fi ohun tí ìwọ kò béèrè fún ọ: ọrọ̀ àti ọlá ní gbogbo ayé rẹ, tí kì yóò sí ẹnìkan nínú àwọn ọba tí yóò dàbí rẹ.
Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.”
Solomoni jí: ó sì mọ̀ pé àlá ni. Ó sì padà sí Jerusalẹmu, ó sì dúró níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà. Nígbà náà ni ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
Nígbà tí gbogbo Israẹli gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, wọ́n sì bẹ̀rù níwájú ọba, nítorí wọ́n ti rí í pé ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe ìdájọ́.
Ọlọ́run sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, àti òye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti ìmọ̀ gbígbòòrò òye tí a kò le è fiwé iyanrìn tí ó wà létí Òkun.
“Ìwọ mọ̀ pé Dafidi baba mi kò le kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, nítorí ogun tí ó wà yí i káàkiri, títí Olúwa fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa Ọlọ́run mi ti fún mi ní ìsinmi ní ibi gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ọ̀tá tàbí ìjàǹbá kan tí ó ṣe.
Nítorí náà mo gbèrò láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi, bí Olúwa ti sọ fún Dafidi baba mi, nígbà tí ó wí pé, ‘Ọmọ rẹ tí èmi yóò gbé ka orí ìtẹ́ rẹ ní ipò rẹ ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’
Nígbà tí Hiramu sì gbọ́ iṣẹ́ Solomoni, inú rẹ̀ sì dùn gidigidi, ó sì wí pé, “Ògo ni fún Olúwa lónìí, nítorí tí ó ti fún Dafidi ní ọlọ́gbọ́n ọmọ láti ṣàkóso àwọn ìlú ńlá yìí.”
Olúwa sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un. Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrín Hiramu àti Solomoni, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn.
Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún (480) lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni lórí Israẹli, ní oṣù Sifi, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé Olúwa.