Skip to content
Nehemiah 11:20-36

Nehemiah 11:20-36

20
Àwọn tókù nínú àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wà ní gbogbo ìlú u Juda, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìní tirẹ̀.
21
Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili ń gbé lórí òkè Ofeli, Siha àti Giṣpa sì ni alábojútó wọn.
22
Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ní Jerusalẹmu ní Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah ọmọ Mika. Ussi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọ́sìn ní ilé Ọlọ́run.
23
Àwọn akọrin wà ní abẹ́ àṣẹ ọba, èyí tí ó n díwọ̀n iṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn.
24
Petahiah ọmọ Meṣesabeli, ọ̀kan nínú àwọn Sera ọmọ Juda ní aṣojú ọba nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ènìyàn náà.
25
Fún ìletò pẹ̀lú oko wọn, díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn Juda tí ń gbé Kiriati-Arba, àti àwọn ìletò agbègbè e rẹ̀, ní Diboni àti ìletò rẹ̀, ní Jekabseeli.
26
Ní Jeṣua, ní Molada, ní Beti-Peleti
27
ní Hasari-Ṣuali, ní Beerṣeba àti àwọn agbègbè rẹ̀.
28
Ní Siklagi, ní Mekona àti àwọn ìletò rẹ̀,
29
ní Ẹni-Rimoni, ní Sora, ní Jarmatu,
30
Sanoa, Adullamu àti àwọn ìletò o wọn, ní Lakiṣi àti àwọn oko rẹ̀, àti ní Aseka àti àwọn ìletò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé láti Beerṣeba títí dé àfonífojì Hinnomu.
31
Àwọn ọmọ Benjamini láti Geba ń gbé ní Mikmasi, Aija, Beteli àti àwọn ìletò rẹ̀.
32
Ní Anatoti, Nobu àti Ananiah,
33
ní Hasori Rama àti Gittaimu,
34
ní Hadidi, Seboimu àti Neballati,
35
ní Lodi àti Ono, àti ní àfonífojì àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà.
36
Nínú ìpín àwọn ọmọ Lefi ni Juda tẹ̀dó sí Benjamini.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options