Nehemiah 11:20-24
20
Àwọn tókù nínú àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wà ní gbogbo ìlú u Juda, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìní tirẹ̀.
21
Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili ń gbé lórí òkè Ofeli, Siha àti Giṣpa sì ni alábojútó wọn.
22
Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ní Jerusalẹmu ní Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah ọmọ Mika. Ussi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọ́sìn ní ilé Ọlọ́run.
23
Àwọn akọrin wà ní abẹ́ àṣẹ ọba, èyí tí ó n díwọ̀n iṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn.
24
Petahiah ọmọ Meṣesabeli, ọ̀kan nínú àwọn Sera ọmọ Juda ní aṣojú ọba nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ènìyàn náà.
Settings