Skip to content
Matiu 24:4-28

Matiu 24:4-28

4
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ.
5
Nítorí ọ̀pọ̀ yóò wá ní orúkọ mi tí wọn yóò máa pe ara wọn ní Kristi náà. Wọn yóò ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà.
6
Ẹ ó máa gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà nítorí nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣe kí ó ma ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe àkókò náà.
7
Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ìyàn àti ilẹ̀ mímì yóò wà ní ibi púpọ̀.
8
Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ó ń bọ̀.
9
“Nígbà náà ni a ó sì dá a yín lóró. A ó pa yín, a ó sì kórìíra yín ni gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ tèmi.
10
Àti pé, ọ̀pọ̀ nínú yín yóò kọsẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣòfófó ara yín, ẹ̀yin yóò kórìíra ara yín pẹ̀lú,
11
ọ̀pọ̀ àwọn èké wòlíì yóò farahàn, wọn yóò tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jẹ.
12
Ẹ̀ṣẹ̀ yóò wà níbi gbogbo, yóò sì sọ ìfẹ́ ọ̀pọ̀ di tútù,
13
ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbàlà.
14
A ó sì wàásù ìyìnrere nípa ìjọba náà yìí ní gbogbo ayé ká, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.
15
“Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ‘ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ,’ tí ó bá dúró ní ibi mímọ́ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e),
16
nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè.
17
Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀.
18
Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn.
19
Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ loyan ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì!
20
Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi.
21
Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí.
22
“Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé. Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú.
23
Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wo Kristi náà,’ tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́.
24
Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ.
25
Wò ó, mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀.
26
“Nítorí náà, bí ẹnìkan bá sọ fún yín pé, ‘Olùgbàlà ti dé,’ àti pé, ‘Ó wà ní aginjù,’ ẹ má ṣe wàhálà láti lọ wò ó, tàbí tí wọ́n bá ní, ó ń fi ara pamọ́ sí iyàrá,” ẹ má ṣe gbà wọn gbọ́.
27
Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́.
28
Nítorí ibikíbi tí òkú bá gbé wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ igún ń kójọpọ̀ sí.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options