Gẹnẹsisi 36:1-19
1
Wọ̀nyí ni ìran Esau, ẹni tí a ń pè ní Edomu.
2
Nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Adah ọmọbìnrin Eloni ará Hiti àti Oholibama, ọmọbìnrin Ana, ọmọ ọmọ Sibeoni ará Hifi.
3
Ó sì tún fẹ́ Basemati ọmọ Iṣmaeli arábìnrin Nebaioti.
4
Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli,
5
Oholibama pẹ̀lú sì bí Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Esau bí ní Kenaani.
6
Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà.
7
Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojú kan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwọn méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn.
8
Báyìí ni Esau (tí a tún mọ̀ sí Edomu) tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè tí Seiri.
9
Èyí ni ìran Esau baba àwọn ará Edomu ní àwọn orílẹ̀-èdè olókè Seiri.
10
Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Esau: Elifasi ọmọ Adah aya Esau àti Reueli, ọmọ Basemati tí í ṣe aya Esau pẹ̀lú.
11
Àwọn ọmọ Elifasi ni ìwọ̀nyí: Temani, Omari, Sefi, Gatamu, àti Kenasi.
12
Elifasi ọmọ Esau sì tún ní àlè tí a ń pè ní Timna pẹ̀lú, òun ló bí Amaleki fún un. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọ Adah aya Esau.
13
Àwọn ọmọ Reueli: Nahati, Sera, Ṣamma àti Missa. Àwọn ni ọmọ ọmọ Basemati aya Esau.
14
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Oholibama ọmọbìnrin Ana ọmọ ọmọ Sibeoni: tí ó bí fún Esau: Jeuṣi, Jalamu àti Kora.
15
Àwọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Esau: àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau, Temani, Omari, Sefi, Kenasi,
16
Kora, Gatamu àti Amaleki. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Elifasi ní Edomu wá, wọ́n jẹ́ ọmọ ọmọ Adah.
17
Wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Esau, ọmọ Rueli: Nahati olórí, Sera olórí, Ṣamma olórí, Missa olórí. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Reueli jáde ní Edomu. Ọmọ ọmọ Basemati aya Esau ni wọ́n jẹ́.
18
Àwọn ọmọ Oholibama aya Esau: Jeuṣi, Jalamu, àti Kora, àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Oholibama ọmọ Ana, ìyàwó Esau wá.
19
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Esau (ti o túmọ̀ sí Edomu). Àwọn wọ̀nyí ni olórí wọn.
Settings