Gẹnẹsisi 36:20-30
20
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Seiri ará Hori tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana,
21
Diṣoni, Eseri, àti Diṣani, àwọn wọ̀nyí olórí ènìyàn Hori, àwọn ọmọ Seiri ni ilẹ̀ Edomu.
22
Àwọn ọmọ Lotani: Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani.
23
Àwọn ọmọ Ṣobali: Alifani, Manahati, Ebali, Ṣefo àti Onamu.
24
Àwọn ọmọ Sibeoni: Aiah àti Ana. Èyí ni Ana tí ó rí ìsun omi gbígbóná ní inú aginjù bí ó ti ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣebeoni baba rẹ̀.
25
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ana: Diṣoni àti Oholibama ọmọbìnrin Ana.
26
Àwọn ọmọ Diṣoni ni: Hemdani, Eṣbani, Itrani àti Kerani.
27
Àwọn ọmọ Eseri: Bilhani, Saafani àti Akani.
28
Àwọn ọmọ Diṣani ni: Usi àti Arani.
29
Àwọn wọ̀nyí ni olórí ìdílé Hori: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana,
30
Diṣoni Eseri, àti Diṣani. Àwọn ni olórí ìdílé àwọn ará Hori gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní ilẹ̀ Seiri.
Settings