Skip to content
Gẹnẹsisi 36:1-8

Gẹnẹsisi 36:1-8

1
Wọ̀nyí ni ìran Esau, ẹni tí a ń pè ní Edomu.
2
Nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Adah ọmọbìnrin Eloni ará Hiti àti Oholibama, ọmọbìnrin Ana, ọmọ ọmọ Sibeoni ará Hifi.
3
Ó sì tún fẹ́ Basemati ọmọ Iṣmaeli arábìnrin Nebaioti.
4
Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli,
5
Oholibama pẹ̀lú sì bí Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Esau bí ní Kenaani.
6
Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà.
7
Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojú kan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwọn méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn.
8
Báyìí ni Esau (tí a tún mọ̀ sí Edomu) tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè tí Seiri.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options