- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Gẹnẹsisi22
Listen to this chapter
0:00
0:00
Ọlọ́run dán Abrahamu wò
1
Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run dán Abrahamu wò, ó pè é, ó sì wí pé, “Abrahamu.” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
2
Ọlọ́run sì wí pé, “Mú ọmọ rẹ, àní Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Moria, kí o sì fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ.”
Ìrìnàjò lọ sí Móráyà
3
Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì ṣẹ́ igi fún ẹbọ sísun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún un.
4
Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta, Abrahamu gbé ojú sókè, ó sì rí ibi tí ó ń lọ ní òkèrè,
5
Abrahamu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ohunkóhun láti sin Ọlọ́run, a ó sì tún padà wá bá a yín.”
6
Abrahamu sì gbé igi ẹbọ sísun náà ru Isaaki, òun fúnra rẹ̀ sì mú iná àti ọ̀bẹ. Bí àwọn méjèèjì ti ń lọ,
7
Isaaki sì sọ fún Abrahamu baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.” Abrahamu sì dalóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.” Isaaki sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?”
8
Abrahamu sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì jùmọ̀ ń lọ.
9
Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Abrahamu, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igi lé e lórí, ó sì di Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà.
10
Abrahamu sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀.
Olúwa pèsè
11
Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa ké sí i láti ọ̀run wá wí pé “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
12
Angẹli Olúwa sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí.”
13
Abrahamu sì gbójú sókè, ó sì rí àgbò kan tí ó fi ìwo há pàǹtírí, ó sì lọ mú un, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀.
14
Abrahamu sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, Jehofah Jire. Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè Olúwa, ni a ó ti pèsè.”
A fi ìbúra múlẹ̀ majẹmu
15
Angẹli Olúwa sì tún pe Abrahamu láti ọ̀run wá lẹ́ẹ̀kejì.
16
Ó sì wí pé, Olúwa wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí,
17
nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn,
18
àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu.”
19
Nígbà náà ni Abrahamu padà tọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn sì padà lọ sí Beerṣeba. Abrahamu sì jókòó ní Beerṣeba.
Àwọn àtọmọdọ́mọ Náhọri
20
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni a wí fún Abrahamu pé, “Milka aya Nahori bí àwọn ọmọkùnrin fún un.
21
Usi àkọ́bí rẹ̀, Busi arákùnrin rẹ̀, Kemueli (baba Aramu).
22
Kesedi, Haso, Pildasi, Jidlafi, àti Betueli.”
23
Betueli sì ni baba Rebeka. Milka sì bí àwọn ọmọ mẹ́jọ wọ̀nyí fún Nahori arákùnrin Abrahamu.
24
Àlè rẹ̀ tí ń jẹ́ Reuma náà bí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí fun un: Teba, Gahamu, Tahasi àti Maaka.
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Reading Width chars
Options
Study Note