Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Wife: Domestic duties of

16 ẹsẹ · 13 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Domestic duties of

  1. Abrahamu sì yára tọ Sara aya rẹ̀ lọ nínú àgọ́, ó wí pé, “Tètè mú òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára mẹ́ta kí o sì pò ó pọ̀, kí o sì ṣe oúnjẹ.”

  2. Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀ Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.

  3. Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò; ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn.

  4. Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn; ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀ àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.

  5. Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á; nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀.

  6. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́.

  7. Ó rí i pé òwò òun pé fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru.

  8. Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú.

  9. O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.

  10. Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.

  11. Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀; ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀.

  12. A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú.

  13. Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò.

  14. Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.

  15. A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀

  16. Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀ kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.