Fò sí àkóónú

Vashti

10 ẹsẹ · 1 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Vashti

  1. Ayaba Faṣti náà ṣe àsè fún àwọn obìnrin ní ààfin ọba Ahaswerusi.

  2. Kí wọn mú ayaba Faṣti wá síwájú rẹ̀, ti òun ti adé ọba rẹ̀, kí ó lè wá fi ẹwà rẹ̀ hàn àwọn ènìyàn àti àwọn ọlọ́lá, nítorí tí ó rẹwà.

  3. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Faṣti kọ̀ láti wá. Nígbà náà ni ọba bínú gidigidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ.

  4. Ó béèrè pé, “Kí ni a lè ṣe sí ayaba Faṣti gẹ́gẹ́ bí òfin? Nítorí kò tẹríba fún àṣẹ ọba Ahaswerusi tí àwọn ìwẹ̀fà ọba sọ fún un.”

  5. Memukani sì dáhùn níwájú ọba àti àwọn ọlọ́lá pé, “Ayaba Faṣti ti ṣe búburú, kì í ṣe sí ọba nìkan ṣùgbọ́n sí gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba Ahaswerusi.

  6. Nítorí ìwà ayaba yìí yóò tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn obìnrin, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ wọn yóò di gígàn lójú u wọn, wọn yóò sì sọ pé, ọba Ahaswerusi pàṣẹ pé kí á mú ayaba Faṣti wá síwájú òun, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti wá.

  7. “Nítorí náà, bí ó bá tọ́ lójú ọba, jẹ́ kí ó gbé àṣẹ ọba jáde, kí ó sì jẹ́ kí ó wà ní àkọsílẹ̀ pẹ̀lú òfin Persia àti Media, èyí tí kò le é parẹ́, pé kí Faṣti kí ó má ṣe wá síwájú ọba Ahaswerusi. Kí ọba sì fi oyè ayaba rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó sàn jù ú lọ.

  8. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Ahaswerusi ọba sì dáwọ́ ìbínú un rẹ̀ dúró, ó rántí i Faṣti àti ohun tí ó ti ṣe àti àṣẹ tí ó pa nípa tirẹ̀.

  9. Nígbà náà kí ọmọbìnrin tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn kí ó jẹ́ ayaba dípò Faṣti.” Ìmọ̀ràn yìí tẹ́ ọba lọ́rùn, ó sì tẹ̀lé e.

  10. Esteri sì wu ọba ju àwọn obìnrin tókù lọ, Ó sì rí ojúrere àti oore-ọ̀fẹ́ gbà ju ti àwọn wúńdíá tókù lọ. Nítorí náà ó fi adé ọba dé e ní orí ó sì fi ṣe ayaba dípò Faṣti.