Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Usury or Interest

24 ẹsẹ · 11 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. “Bí ìwọ bá yá ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn mi tí ìyà ń jẹ láàrín yín lówó, má ṣe dàbí ayánilówó, kí o má sì gba èlé.

  2. “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá tálákà tí kò sì le è pèsè fún àìní ara rẹ̀, ẹ pèsè fún un bí ẹ ti ń ṣe fún àwọn àlejò tàbí àwọn tí ẹ gbà sílé: kí ó ba à le è máa gbé láàrín yín.

  3. Ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé kankan lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ bẹ̀rù Olúwa kí arákùnrin yín le è máa gbé láàrín yín.

  4. Ẹ má ṣe gba èlé lórí owó tí ẹ yá a bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ èrè lórí oúnjẹ tí ẹ tà fún un.

  5. Ìwọ kò gbọdọ̀ ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá.

  6. Ìwọ lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Israẹli, nítorí kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

  7. Èmi bínú gidigidi nígbà tí mo gbọ́ igbe wọn àti àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí.

  8. Mo rò wọ́n wò ní ọkàn mi mo sì fi ẹ̀sùn kan ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè. Mo sọ fún wọn pé, ẹ̀yin ń gba owó èlé lọ́wọ́ àwọn ará ìlú u yín! Nítorí náà mo pe àpéjọ ńlá láti bá wọn wí.

  9. Nítorí náà, mo tẹ̀síwájú pé, “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe kò dára. Kò ha yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run bí, láti yẹra fún ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí í ṣe ọ̀tá wa?

  10. Èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú ń yá àwọn ènìyàn lówó àti oúnjẹ. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a dáwọ́ owó èlé gbígbà yìí dúró!

  11. Ẹ fún wọn ní oko wọn, ọgbà àjàrà wọn, ọgbà olifi wọn àti ilé e wọn pẹ̀lú owó èlé tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ wọn ìdá ọgọ́rùn-ún owó, oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ wọn padà kíákíá.”

  12. Wọ́n wí pé, “Àwa yóò dá a padà. Àwa kì yóò sì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wọn mọ́. Àwa yóò ṣe bí o ti wí.” Nígbà náà mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè búra láti jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ti ṣe ìlérí.

  13. Mo sì gbọn ìṣẹ́tí aṣọ mi, mo wí pé, “Báyìí ni kí Ọlọ́run gbọn olúkúlùkù ènìyàn tí kò bá pa ìlérí yìí mọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ ìní i rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí a gbọn irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kí ó sì ṣófo!” Gbogbo ìjọ ènìyàn sì wí pé, “Àmín,” wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa. Àwọn ènìyàn náà sì ṣe bí wọ́n ti ṣe ìlérí.

  14. tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí ni a kì yóò mì láéláé.

  15. Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù ń kó jọ fún ẹlòmíràn, tí yóò ní àánú àwọn tálákà.

  16. Kíyèsi i, Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayé yóò sì pa á run òun yóò pa ojú u rẹ̀ rẹ́ yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—

  17. bákan náà ni yóò sì rí fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn, fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀, fún ìyá-ilé àti ọmọbìnrin, fún olùtà àti olùrà, fún ayáni àti atọrọ fún ayánilówó àti onígbèsè.

  18. Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi, ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà! Èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.

  19. Ẹni tí kò fi fún ni láti gba ẹ̀dá, tàbí kò gba èlé tó pọ̀jù. Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ òtítọ́ láàrín ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀.

  20. Tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lóòtítọ́ àti lódodo. Ó jẹ́ olódodo, yóò yè nítòótọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.

  21. Ó ń fi owó ya ni pẹ̀lú èlé, ó sì tún ń gba èlé tó pọ̀jù. Ǹjẹ́ irú ọkùnrin yìí wa le è yè bí? Òun kì yóò wá láààyè! Nítorí pé òun ti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, kíkú ni yóò kú, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wá lórí rẹ̀.

  22. Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀; ìwọ gba èlé ìlọ́po láti mú aláìṣòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ. Ìwọ sì ti gbàgbé èmi; ni Olúwa Olódùmarè wí.

  23. Nígbà náà ìwọ ìbá kúkú fi owó mi sí ilé ìfowópamọ́ tí èmi bá dé èmi ìbá le gba owó mi pẹ̀lú èrè.

  24. Èéha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowópamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’