Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Tribe Of Simeon: Bounds of their inheritance with cities and villages
Àwọn ẹsẹ nípa Bounds of their inheritance with cities and villages
Lára ìpín wọn ní: Beerṣeba (tàbí Ṣeba), Molada,
Hasari-Ṣuali, Bala, Esemu,
Eltoladi, Betuli, Horma,
Siklagi, Beti-Markaboti, Hasari Susa,
Beti-Lebaoti àti Ṣarueli, ìlú wọn jẹ́ mẹ́tàlá àti ìletò wọn.
Aini, Rimoni, Eteri àti Aṣani, ìlú wọn jẹ́ mẹ́rin àti ìletò wọn,
àti gbogbo àwọn agbègbè ìlú wọ̀nyí títí dé Baalati-Beeri (Rama ní gúúsù). Èyí ni ilẹ̀ ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Simeoni, agbo ilé, ní agbo ilé.
Wọ́n sì ń gbé ní Beerṣeba, Molada, Hasari-Ṣuali,
àti ní Biliha, àti ní Esemu, àti ní Toladi,
Betueli, Horma, Siklagi,
Beti-Markaboti Hormah; Hasari Susimu, Beti-Biri àti Ṣaraimi. Àwọn wọ̀nyí ni ìlú wọn títí di ìgbà ọba Dafidi,
agbègbè ìlú wọn ni Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni, Aṣani àwọn ìlú márùn-ún,
àti gbogbo ìletò wọn, tí ó wà yí ìlú náà ká, dé Baali. Àwọn wọ̀nyí ni ibùgbé wọn. Àti ìtàn ìdílé wọ́n.