Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Rich

145 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó, tí ó lágbára, wọ́n sì ń sọkún sí aya arákùnrin wọn.

  2. Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

  3. Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ, ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn; wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,

  4. wọ́n sanra wọ́n sì ń dán. Ìwà búburú wọn kò sì lópin; wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀. Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.

  5. Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi lára orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

  6. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbára nítorí agbára rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀.

  7. Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé ni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìṣòdodo. Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀, àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè.

  8. “Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìṣòdodo, àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́ tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán láìsan owó iṣẹ́ wọn fún wọn.

  9. Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara mi àwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀, ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’ A ó sì fi igi kedari bò ó, a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́.

  10. “Ìwọ ó ha jẹ ọba kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari? Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu? Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo, nítorí náà ó dára fún un.

  11. Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní, ohun gbogbo sì dára fún un. Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?” ni Olúwa wí.

  12. “Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ wà lára èrè àìṣòótọ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”

  13. Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda: “Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’ Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe ọlọ́lá!’

  14. A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a wọ́ sọnù láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu.”

  15. “ ‘Wọn yóò dà fàdákà wọn sí ojú pópó, wúrà wọn yóò sì dàbí èérí fàdákà àti wúrà wọn kò ní le gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná Olúwa. Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.

  16. Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ, ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, ọkàn rẹ gbé sókè, nítorí ọrọ̀ rẹ.

  17. Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá.

  18. Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì. Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini. Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ? Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí?

  19. Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú, ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí.

  20. Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ.

  21. Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin.

  22. Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan àti ìkunra tí o dára jùlọ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro.

  23. Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá; àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn?

  24. Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọn kì yóò sì le gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.” Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi iná ìjowú rẹ̀ parun, nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sí gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ayé.

  25. Nígbà náà, ní Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.”