Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Power of God

89 ẹsẹ · 51 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ohùn Olúwa fa igi kedari; Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.

  2. nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.

  3. Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo gbọ́ èyí pé, “Ti Ọlọ́run ni agbára,

  4. Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda. Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ, òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi, ara mi fà sí ọ, ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀ níbi tí kò sí omi.

  5. Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́, mo rí agbára àti ògo rẹ.

  6. ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ, tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára,

  7. Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀, ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela.

  8. Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè, tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.

  9. Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ; Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ. Olùbùkún ní Ọlọ́run!

  10. Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá síwájú rẹ, gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára rẹ ìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bi ikú.

  11. Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.

  12. Ìwọ ní apá agbára; agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

  13. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

  14. Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀.

  15. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  16. Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, síbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.

  17. Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé, nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta ayérayé náà.

  18. Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun tí mo ti ṣe; ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!

  19. Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.

  20. Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”

  21. Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run; nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn dìde sókè papọ̀.

  22. Olúwa yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí ìgbàlà Ọlọ́run wa.

  23. ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀ láti wà ní apá ọ̀tún Mose, ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn, láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀,

  24. Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?” ni Olúwa wí. “Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ó wárìrì níwájú mi bí? Mo fi yanrìn pààlà òkun, èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé. Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀; wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.

  25. Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀, ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀.