Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The, or Immediate Government By God Theocracy

98 ẹsẹ · 15 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, lọ, èmi yóò rán ọ sí Farao láti kó àwọn ènìyàn Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.”

  2. “Sọ fún àwọn ará ilé Israẹli, ‘Èmi ni Olúwa, Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúrò ní oko ẹrú wọn. Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà (àwọn iṣẹ́ ìyanu) àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá.

  3. Èmi yóò mú un yín bí ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti.

  4. Olúwa sì sọ fun Mose pé. “Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Joṣua pẹ̀lú; nítorí èmi yóò pa ìrántí Amaleki run pátápátá kúrò lábẹ́ ọ̀run.”

  5. Mose sì tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì sọ orúkọ pẹpẹ náà ní Olúwa ni Àsíá mi.

  6. Ó wí pé, “A gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ Olúwa. Olúwa yóò bá Amaleki jagun láti ìran dé ìran.”

  7. ‘Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Ejibiti, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì.

  8. Nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́ràn sí mi dé ojú àmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi.

  9. Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ̀ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀-èdè mímọ́.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.”

  10. “Nígbà náà ni ìwọ yóò jẹ́ kí wọn kọ́ ibi mímọ́ fún mi. Èmi yóò sì máa gbé ní àárín wọn.

  11. “Ìwọ sì mú Aaroni arákùnrin rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, mú un kúrò ni àárín àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ Nadabu, Abihu, Eleasari, àti Itamari, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

  12. Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ.

  13. Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti: “wúrà, fàdákà àti idẹ;

  14. aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára; àti irun ewúrẹ́;

  15. awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù; odò igi kasia;

  16. òróró olifi fún títan iná; olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn;

  17. òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà.

  18. “Gbogbo ẹni tí ó ní ọgbọ́n láàrín yín, kí ó wa, kí ó sì wá ṣe gbogbo ohun tí Olúwa ti pàṣẹ:

  19. “àgọ́ náà pẹ̀lú àgọ́ rẹ àti ìbòrí rẹ̀, kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ọ̀wọ́n rẹ̀ àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;

  20. Àpótí náà pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀, ìbò àánú àti aṣọ títa náà tí ó síji bò ó.

  21. Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà.

  22. Ọ̀pá fìtílà tí ó wà fún títanná pẹ̀lú ohun èlò rẹ̀, fìtílà àti òróró fún títanná.

  23. Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn; aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu-ọ̀nà sí àgọ́ náà.

  24. Pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú ojú ààrò idẹ rẹ̀, òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; agbada idẹ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀.

  25. Aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú, ọ̀wọ́n àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà.