Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The High Priest

142 ẹsẹ · 65 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹni tí ó sun wọ́n yóò sì fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì wẹ ara rẹ̀, lẹ́yìn èyí ni ó tó le wọ ibùdó.

  2. “Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín, pé ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ni ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan, yálà onílé tàbí àlejò tí ó ń gbé pẹ̀lú yín.

  3. Torí pé ní ọjọ́ yìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún yín láti sọ yín di mímọ́, kí ẹ̀yin bá à le mọ́ níwájú Olúwa yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo.

  4. Ọjọ́ yìí yóò jẹ́ ọjọ́ ìsinmi pátápátá fún un yín, ẹ̀yin yóò sì ṣẹ́ ara yín. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé.

  5. Àlùfáà náà tí a ti fi òróró yàn tí a sì ti sọ di mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ilé ìsìn ní ipò baba rẹ̀, òun ni kí ó ṣe ètùtù, yóò sì wọ aṣọ funfun gbòò àní aṣọ mímọ́ náà, òun yóò sì ṣe ètùtù.

  6. Yóò sì ṣe ètùtù fún Ibi Mímọ́ Jùlọ, fún ìpàdé àti fún pẹpẹ, yóò sì ṣe ètùtù fún àlùfáà àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ènìyàn náà.

  7. “Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún yín: láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ará Israẹli fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́dún.” Ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  8. Olúwa sọ fún Mose wí pe, “Bá àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú wọn kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí àwọn ènìyàn wọn tí ó kù.

  9. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe àwọn tí ó súnmọ́ ọn bí ìyá rẹ̀, baba rẹ̀, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin, àti arákùnrin rẹ̀.

  10. Tàbí fún arábìnrin rẹ̀ tí kò ì tí ì wọ ilé ọkọ tí ó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí tí arábìnrin bẹ́ẹ̀, ó lè sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́.

  11. Nítorí tí ó jẹ́ olórí, òun kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ ba ara rẹ̀ jẹ́ láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

  12. “ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ fá irun orí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ rẹ́ irùngbọ̀n rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara rẹ̀ láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀.

  13. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n má ba à sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di àìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń fi iná sun ẹbọ sí Olúwa wọn, ti ó jẹ oúnjẹ Ọlọ́run wọn. Nítorí náà wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.

  14. “ ‘Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ panṣágà tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn.

  15. Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ máa kà wọ́n sí mímọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ oúnjẹ fún mi. Èmi ni Olúwa, mo jẹ́ mímọ́, mo sì ya àwọn ènìyàn mi sí mímọ́.

  16. “ ‘Bí ọmọbìnrin àlùfáà kan bá fi iṣẹ́ àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ó dójútì baba rẹ̀, iná ni a ó dá sun ún.

  17. “ ‘Lẹ́yìn tí a ti fi òróró yan olórí àlùfáà láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀, tí a sì ti fi àmì òróró yàn án láti máa wọ aṣọ àlùfáà, ó gbọdọ̀ tọ́jú irun orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀.

  18. Kí ó ma ṣe wọlé tọ òkú lọ, kí ó má ṣe sọ ará rẹ di àìmọ́ nítorí baba tàbí nítorí ìyá rẹ̀.

  19. Kò gbọdọ̀ kúrò ní ibi mímọ́ Ọlọ́run tàbí kí ó sọ ọ́ di aláìmọ́ torí pé a ti fi ìfòróróyàn Ọlọ́run yà á sí mímọ́. Èmi ni Olúwa.

  20. Wọn yóò ṣe tiwọn ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì. Wọn yóò jẹ ẹran náà, pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewúro.

  21. Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣe àjọ ìrékọjá.

  22. Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ Olúwa wá ní àsìkò tí ó yẹ. Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

  23. “ ‘Bí àlejò tí ń gbé láàrín yín bá fẹ́ ṣe àjọ ìrékọjá Olúwa, ó gbọdọ̀ pa á mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin rẹ̀. Ìlànà kan náà ni kí ẹ ní fún àlejò àti àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ yín.’ ”

  24. Ní ọjọ́ tí wọ́n gbé àgọ́ ró, èyí tí í ṣe àgọ́ ẹ̀rí, dúró, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ bò ó mọ́lẹ̀. Ìkùùkuu náà sì dàbí iná ní orí àgọ́ láti ìrọ̀lẹ́ títí di òwúrọ̀.

  25. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí nígbà gbogbo; ìkùùkuu bò ó, àti pé ní alẹ́ ìrísí rẹ̀ sì dàbí iná.