Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The First Temple

365 ẹsẹ · 72 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ní ti àwọn àlejò tí kì í ṣe Israẹli ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ rẹ,

  2. nítorí tí àwọn ènìyàn yóò gbọ́ orúkọ ńlá rẹ, àti ọwọ́ agbára rẹ, àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá sì wá, tí ó sì gbàdúrà sí ìhà ilé yìí,

  3. nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí àlejò náà yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo ènìyàn ní ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì máa bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Israẹli, ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì le mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a fi pe ilé yìí tí mo kọ́.

  4. “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá jáde lọ sí ogun sí àwọn ọ̀tá wọn, níbikíbi tí ìwọ bá rán wọn, nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí Olúwa sí ìhà ìlú tí ìwọ ti yàn àti síhà ilé tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ,

  5. nígbà náà ni kí o gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró.

  6. “Nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ sí ọ, nítorí kò sí ẹnìkan tí kì í ṣẹ̀, tí ìwọ sì bínú sí wọn, tí ìwọ sì fi wọ́n lé ọ̀tá lọ́wọ́, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ wọn, jíjìnnà tàbí nítòsí;

  7. bí wọ́n bá ní ìyípadà ọkàn ní ilẹ̀ níbi tí a kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n bá sì ronúpìwàdà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ sí ọ ní ilẹ̀ àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀, àwa ti ṣe ohun tí kò tọ́, àwa ti ṣe búburú’;

  8. bí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà àti gbogbo ọkàn wọn yípadà sí ọ, ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ sí ìhà ilẹ̀ wọn tí ìwọ ti fi fún àwọn baba wọn, ìlú tí ìwọ ti yàn, àti ilé tí èmi kọ́ fún orúkọ rẹ;

  9. nígbà náà ni kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn ní ọ̀run, ní ibùgbé rẹ, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró.

  10. Kí o sì dáríjì àwọn ènìyàn rẹ, tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ; dárí gbogbo ìrékọjá wọn tí wọ́n ṣe sí ọ jì, kí o sì bá àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ wí, kí wọn kí ó lè ṣàánú fún wọn;

  11. nítorí ènìyàn rẹ àti ìní rẹ ni wọ́n, àwọn ẹni tí ìwọ ti mú ti Ejibiti jáde wá, láti inú irin ìléru.

  12. “Jẹ́ kí ojú rẹ ṣí sí ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, àti sí ẹ̀bẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ Israẹli, kí o sì tẹ́tí sílẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá kégbe sí ọ.

  13. Nítorí tí ìwọ ti yà wọ́n kúrò nínú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, láti máa jẹ́ ìní rẹ, bí ìwọ ti sọ láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ, nígbà tí ìwọ Olúwa Olódùmarè, mú àwọn baba wa ti Ejibiti jáde wá.”

  14. Nígbà tí Solomoni ti parí gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ yìí sí Olúwa tán, ó dìde kúrò lórí eékún rẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa níbi tí ó ti kúnlẹ̀ tí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run

  15. Ó sì dìde dúró ó sì fi ohùn rara súre fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli wí pé,

  16. “Ìbùkún ni fún Olúwa tí ó ti fi ìsinmi fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀ bí ó ti ṣèlérí. Kò sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí rere tí ó ti ṣe láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ̀ wá.

  17. Kí Olúwa Ọlọ́run wa kí ó wà pẹ̀lú wa bí ó ti wà pẹ̀lú àwọn baba wa; kí ó má sì ṣe fi wá sílẹ̀ tàbí kọ̀ wá sílẹ̀.

  18. Kí ó fa ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti máa rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, tí ó ti pàṣẹ fún àwọn baba wa.

  19. Àti kí ó sì jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí, tí mo ti gbà ní àdúrà níwájú Olúwa, kí ó wà nítòsí Olúwa Ọlọ́run wa ní ọ̀sán àti ní òru, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró àti ọ̀rọ̀ Israẹli ènìyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àìní wa ojoojúmọ́,

  20. kí gbogbo ènìyàn ayé lè mọ̀ pé Olúwa òun ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn.

  21. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ọkàn yín pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run wa, láti máa rìn nínú àṣẹ rẹ̀ àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, bí i ti òní yìí.”

  22. Nígbà náà ni ọba àti gbogbo Israẹli rú ẹbọ níwájú Olúwa.

  23. Solomoni rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa: ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ya ilé Olúwa sí mímọ́.

  24. Ní ọjọ́ kan náà ni ọba ya àgbàlá àárín tí ń bẹ níwájú ilé Olúwa sí mímọ́, níbẹ̀ ni ó sì rú ẹbọ sísun àti ọrẹ oúnjẹ, àti ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ń bẹ níwájú Olúwa kéré jù láti gba ẹbọ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọrẹ ẹbọ àlàáfíà.

  25. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe àpéjọ nígbà náà, àti gbogbo Israẹli pẹ̀lú rẹ̀, àjọ ńlá ńlá ni, láti ìwọ Hamati títí dé odò Ejibiti. Wọ́n sì ṣàjọyọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ọjọ́ méje àti ọjọ́ méje sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá papọ̀.