Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Scoffing

58 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bẹ́ẹ̀ àwọn oníṣẹ́ tí ń sáré lọ pẹ̀lú ìwé láti ọwọ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ sí gbogbo Israẹli àti Juda; àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, wí pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ yí padà sí Olúwa Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki, àti Israẹli, òun ó sì yípadà sí àwọn ìyókù nínú yín, tí ó sálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba Asiria.

  2. Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe dàbí àwọn baba yín, àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn, nítorí náà ní ó ṣe fi wọ́n fún ìdahoro bí ẹ̀yin ti rí.

  3. Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣe ọlọ́rùn líle, bí àwọn baba yín, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín lọ́wọ́ fún Olúwa, kí ẹ sì wọ inú ibi mímọ́ rẹ̀ lọ, ti òun ti ìyàsímímọ́ títí láé. Kí ẹ sì sin Olúwa, Ọlọ́run yín kí gbígbóná ìbínú rẹ̀ kí ó lè yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín.

  4. Nítorí bí ẹ̀yin bá tún yípadà sí Olúwa, àwọn arákùnrin yín, àti àwọn ọmọ yín, yóò rí àánú níwájú àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, kí wọn kí ó lè tún padà wá sí ilẹ̀ yí: nítorí Olúwa Ọlọ́run yín, oníyọnu àti aláàánú ni, kì yóò sì yí ojú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ yín, bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀.”

  5. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ náà kọjá láti ìlú dé ìlú, ní ilẹ̀ Efraimu àti Manase títí dé Sebuluni, ṣùgbọ́n wọ́n fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n sì gàn wọ́n.

  6. Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùn sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣẹ̀sín títí tí ìbínú Olúwa fi ru sórí wọn, sí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì ṣí àtúnṣe.

  7. Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’ Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ.

  8. Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in? Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?

  9. Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu, tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi?

  10. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà, tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú, ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.

  11. Oúnjẹ mi ni omijé mi ní ọ̀sán àti ní òru, nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé, “Ọlọ́run rẹ dà?”

  12. Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí, bí wọn ti ń béèrè ní gbogbo ọjọ́. “Níbo ni Ọlọ́run rẹ wà?”

  13. Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀? Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?”

  14. Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?

  15. Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde, odò sì sàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀?”

  16. nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo,

  17. Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀; wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.

  18. “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó? Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó? Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀?

  19. níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi, tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,

  20. Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́, ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀.

  21. Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè: bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”

  22. Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí.

  23. Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá, ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.

  24. Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere.

  25. A ti pèsè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn; àti pàṣán fún ẹ̀yìn àwọn aṣiwèrè.