Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sabbath

239 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.

  2. Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ, Olúwa, nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé; gbogbo àwọn olùṣe búburú ni a ó fọ́nká.

  3. Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó; òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.

  4. Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi; ìparun sí àwọn ènìyàn búburú tí ó dìde sí mi.

  5. Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ, wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni,

  6. tí a gbìn sí ilé Olúwa, Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.

  7. Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó, wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,

  8. láti fihàn pé, “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa; òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú kankan nínú rẹ̀.”

  9. Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá: ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.

  10. Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́! Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi, oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ, Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí.

  11. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí, àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin, tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”

  12. Nítorí pé báyìí ni Olúwa wí: “Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin

  13. fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀ ìrántí kan àti orúkọ kan tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin, Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé tí a kì yóò ké kúrò.

  14. Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwa láti sìn ín, láti fẹ́ orúkọ Olúwa àti láti foríbalẹ̀ fún un gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́ àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—

  15. àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi, èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn, ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi; nítorí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”

  16. “Bí ìwọ bá pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́, àti ṣíṣe bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi, bí ìwọ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ohun dídùn àti ọjọ́ mímọ́ Olúwa ní ohun ọ̀wọ̀ àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọ àti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbí kí o máa sọ̀rọ̀ aláìníláárí,

  17. nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú Olúwa rẹ, èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé, àti láti máa jàdídùn ìní ti Jakọbu baba rẹ.” Ẹnu Olúwa ni ó ti sọ̀rọ̀.

  18. Láti oṣù tuntun kan dé òmíràn àti láti ọjọ́ ìsinmi kan dé òmíràn, ni gbogbo ọmọ ènìyàn yóò wá, wọn yóò sì tẹríba níwájú mi,” ni Olúwa wí.

  19. Báyìí ni Olúwa wí, “Ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu.

  20. Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.”

  21. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsi láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ẹnu-bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà.

  22. Nígbà náà ni ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba ẹnu ibodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé.

  23. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ẹnu ibodè Jerusalẹmu wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu-bodè Jerusalẹmu tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”

  24. Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ ni Jerusalẹmu rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀ tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́. Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, kò sì ṣí olùrànlọ́wọ́ fún un. Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ó wọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà.

  25. Ó mú ìparun bá ibi mímọ́, ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run. Olúwa ti mú Sioni gbàgbé àjọ̀dún tí a yàn àti ọ̀sẹ̀ tí ó yàn; nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run ọba àti olórí àlùfáà.