Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sabbath

239 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe.

  2. Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.

  3. Ní ọjọ́ kẹfà, ki wọn kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń ko ni ojoojúmọ́ tẹ́lẹ̀.”

  4. Ní ọjọ́ kẹfà, wọ́n kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń kó tẹ́lẹ̀: òsùwọ̀n omeri méjì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan; àwọn olórí ìjọ ènìyàn sì wá, wọ́n sì sọ èyí fún Mose.

  5. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ọ̀la jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ìsinmi mímọ́ fún Olúwa. Ẹ yan èyí ti ẹ̀yin ní yan, kí ẹ sì bọ èyí ti ẹ̀yin ní bọ̀. Ẹ tọ́jú èyí ti ó kù sílẹ̀, kí ẹ pa á mọ́ di òwúrọ̀.’ ”

  6. Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mose ti pàṣẹ; kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin.

  7. Mose sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ ẹ́ ní òní nítorí òní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi Olúwa. Ẹ̀yin kò ni rí i ni orí ilẹ̀ ní ọjọ́ òní.

  8. Ní ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi kó o, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ keje ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí i fún un yín ni ọjọ́ náà.”

  9. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó.

  10. Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́?

  11. Wò ó? Olúwa ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni oúnjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọ̀ọ̀kan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.”

  12. Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje.

  13. Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́.

  14. Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,

  15. ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ, tí ń bẹ nínú ibodè rẹ.

  16. Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ó sì sinmi ní ọjọ́ keje: nítorí náà ni Olúwa ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́.

  17. “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì sinmi ní ọjọ́ keje, kí akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ bá à lè ní ìsinmi, kí a sì tú ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àlejò ti ń gbé ni ilé rẹ lára.

  18. “Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.

  19. “ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a yóò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a yóò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ.

  20. Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ́.

  21. Nítorí náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóò ṣe máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíran tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mú títí láé.

  22. Yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti àwọn ọmọ Israẹli títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’ ”

  23. “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje ìwọ yóò sinmi; kódà ní àkókò ìfúnrúgbìn àti ní àkókò ìkórè ìwọ gbọdọ̀ sinmi.

  24. Fún ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi ni sí Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ni ọjọ́ náà ní a ó pa.

  25. Ẹ má ṣe dáná kankan ní ibùgbé yín ní ọjọ́ ìsinmi.”