Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sabbath: Sacrifices on
Àwọn ẹsẹ nípa Sacrifices on
“ ‘Ní ọjọ́ ìsinmi, pèsè akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan tí kò lábùkù, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ohun jíjẹ tí i ṣe ìdá méjì nínú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò.
Èyí ni ẹbọ sísun fún gbogbo ọjọ́ ìsinmi kọ̀ọ̀kan, ní àfikún pẹ̀lú ẹbọ sísun àti ẹbọ ohun mímu.
Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ-aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmi ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù.
Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ efa kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú efa kọ̀ọ̀kan.