Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Responsibility: Personal

13 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Personal

  1. Ọkàn tí ó bá ṣẹ̀ ní yóò kú. Ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni baba náà kò ní ru ẹ̀bi ọmọ rẹ̀. Ìwà rere ènìyàn rere yóò wà lórí rẹ̀, ìwà búburú ti ènìyàn búburú náà la ó kà sí i lọ́rùn.

  2. “Nítorí náà, ilé Israẹli, èmi yóò da yín lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá ṣe rí ni Olúwa Olódùmarè wí. Ẹ yípadà! Kí ẹ si yí kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ìrékọjá kì yóò jẹ́ ọ̀nà ìṣubú yín.

  3. Nítorí nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín ni a fi dá yin láre, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín sì ni a ó fi dá yin lẹ́bi.”

  4. Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fọ́jú, ẹ̀yin kì bá tí lẹ́sẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa ríran,’ nítorí náà ẹ̀ṣẹ̀ yín wà síbẹ̀.

  5. Ìbá ṣe pé èmi kò ti wá kí n sì ti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n di aláìríwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  6. Ẹni tí ó bá kórìíra mi, ó kórìíra Baba mi pẹ̀lú.

  7. Ìbá ṣe pé èmi kò ti ṣe iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì láàrín wọn tí ẹlòmíràn kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n sì rí, wọ́n sì kórìíra èmi àti Baba mi.

  8. Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bu omi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó.

  9. Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fihàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olúkúlùkù ṣe wò.

  10. Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀.

  11. Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù, ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n bí ìgbà tí ènìyàn bá la àárín iná kọjá.

  12. Nítorí pé olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ara rẹ̀.

  13. Èmi o pa àwọn ọmọ rẹ̀ run; gbogbo ìjọ ni yóò sì mọ̀ pé, èmi ni ẹni tí ń wádìí inú àti ọkàn, èmi ó sì fi fún olúkúlùkù yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.