Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pharaoh

35 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Josiah ti tún ilẹ̀ náà ṣetán, Neko ọba Ejibiti gòkè lọ láti bá Karkemiṣi jà lórí odo Eufurate, Josiah sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà.

  2. Ṣùgbọ́n Neko rán ìránṣẹ́ sí i wí pé, “Ìjà wo ni ó ń bẹ láàrín èmi àti ìwọ, ọba Juda? Kì í ṣe ìwọ ni èmi tọ̀ wá ní àkókò yìí, ṣùgbọ́n, ilé pẹ̀lú èyí ti mo bá níjà. Ọlọ́run ti sọ fún mi láti yára àti láti dúró nípa ṣíṣe ìdènà Ọlọ́run, ẹni tí ó wà pẹ̀lú mi, kí òun má bá a pa ọ́ run.”

  3. Josiah, kò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ara rẹ̀ dà kí ó le bá a jà, kó sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Neko láti ẹnu Ọlọ́run wá, ó sì wá jagun ní àfonífojì Megido.

  4. Tafàtafà sì ta ọfà sí ọba Josiah, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè pé, “Ẹ gbé mi kúrò, èmi ti gba ọgbẹ́ gidigidi.”

  5. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbé e jáde kúrò nínú kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n sì gbé e sínú kẹ̀kẹ́ mìíràn, wọ́n sì gbé e wá sí Jerusalẹmu, níbi tí ó ti kú, wọ́n sì sin ín sínú ọ̀kan nínú àwọn ibojì àwọn baba rẹ̀, gbogbo Juda àti gbogbo Jerusalẹmu sì ṣọ̀fọ̀ Josiah.

  6. Ọba Ejibiti yọ kúrò lórí ìtẹ́ ní Jerusalẹmu, ó sì bù fún un lórí Juda, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti tálẹ́ǹtì wúrà kan.

  7. Ọba Ejibiti sì mú Eliakimu, arákùnrin Joahasi, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu, ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu, ṣùgbọ́n Neko mú Joahasi arákùnrin Eliakimu lọ sí Ejibiti.

  8. Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú; ó fi ọba bú nítorí tiwọn:

  9. Nípa Ejibiti. Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:

  10. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tó tọ wòlíì Jeremiah wá nípa àwọn Filistini, kí ó tó di pé Farao dojúkọ Gasa.