Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Palaces

48 ẹsẹ · 36 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kí ibùjókòó wọn di ahoro; kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.

  2. Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀, ibi gíga, gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.

  3. Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn, àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.

  4. Ọmọnílé fi ọwọ́ rẹ̀ dì mú, síbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.

  5. Bí òun bá jẹ́ ògiri, àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí. Bí òun bá jẹ́ ìlẹ̀kùn, àwa yóò fi pákó kedari dí i.

  6. Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn, àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.

  7. Ilé olódi ni a ó kọ̀sílẹ̀, ìlù aláriwo ni a ó kọ̀ tì; ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ihò títí láéláé, ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápá oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,

  8. Ẹ̀gún yóò sì hù jáde nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí, ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀. Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá àti àgbàlá fún àwọn òwìwí.

  9. Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé ó sì ti wọ odi alágbára wa ó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní àdúgbò àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba.

  10. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ẹnu ibodè Jerusalẹmu wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu-bodè Jerusalẹmu tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”

  11. Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro. Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀.

  12. Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá.

  13. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò ní àbùkù ara, tí wọ́n rẹwà, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ hàn, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí òye tètè ń yé àti àwọn tí ó kún ojú òsùwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba kí ó kọ́ wọ́n ní èdè àti onírúurú ẹ̀kọ́ ìwé ti àwọn Babeli.

  14. Ọba pèsè oúnjẹ ojoojúmọ́ àti wáìnì láti orí tábìlì i rẹ̀ fún wọn, ó sì kọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ fún ọba.

  15. Èmi Nebukadnessari wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà.

  16. Nígbà náà ni ọba padà sí ààfin rẹ̀, ó sì lo gbogbo òru náà láì jẹun, kò sì gbọ́ orin kankan, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le è sùn ní òru ọjọ́ náà.

  17. Ẹ kéde ní ààfin Aṣdodu àti ní ààfin ní ilẹ̀ Ejibiti. “Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samaria; kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrín rẹ̀ àti ìnilára láàrín àwọn ènìyàn rẹ.”

  18. “Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí, “àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”

  19. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run; yóò wó ibi gíga yín palẹ̀ a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”

  20. Òun yóò sì jẹ́ àlàáfíà wọn. Nígbà tí àwọn Asiria bá gbógun sí ilẹ̀ wa tí wọ́n sì ń yan lórí odi alágbára wa, nígbà náà ni a ó gbé olùṣọ́-àgùntàn méje dìde sí i, àti olórí ènìyàn mẹ́jọ.

  21. Ṣùgbọ́n Peteru ń tẹ̀lé e lókèèrè. Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà. Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́. Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jesu.

  22. Ṣùgbọ́n kín ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba!

  23. “Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ni ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà.