Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Offence: The low station of Christ

7 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ nípa The low station of Christ

  1. Ta ni ó ti gba ìròyìn in wa gbọ́ àti ta ni a ti fi apá Olúwa hàn fún?

  2. Òun dàgbàsókè níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ irúgbìn, àti gẹ́gẹ́ bí i gbòǹgbò tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀. Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀ tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́rí i rẹ̀.

  3. A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí. Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá.

  4. Ó wá sí ìlú òun tìkára rẹ̀, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú Sinagọgu, ẹnu sì yà wọ́n. Wọ́n béèrè pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí ti mú ọgbọ́n yìí àti iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí wá?

  5. Kì í ha ṣe ọmọ gbẹ́nàgbẹ́nà ni èyí bí? Ìyá rẹ̀ ha kọ́ ni à ń pè ní Maria bí? Arákùnrin rẹ̀ ha kọ́ ni Jakọbu, Josẹfu, Simoni àti Judasi bí?

  6. Àwọn arábìnrin rẹ̀ gbogbo ha kọ́ ni ó ń bá wa gbé níhìn-ín yìí, nígbà náà níbo ni ọkùnrin yìí ti rí àwọn nǹkan wọ̀nyí?”

  7. Inú bí wọn sí i. Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Wòlíì a máa lọ́lá ní ibòmíràn, àfi ní ilé ara rẹ̀ àti ní ìlú ara rẹ̀ nìkan ni wòlíì kò ti lọ́lá.”