Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Offence: Punishment for occasioning

5 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Punishment for occasioning

  1. Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn níwájú àwọn ère wọn, tí wọn sì mu ilé Israẹli ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí náà, Èmi tí búra nípa nína ọwọ́ sókè pé, wọn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ní Olúwa Olódùmarè wí.

  2. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yapa kúrò ní ọ̀nà náà; ẹ̀yin sì ti fi ìkọ́ni yín mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀; ẹ̀yin ti ba májẹ̀mú tí mo da pẹ̀lú Lefi jẹ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  3. “Nítorí náà ni èmi pẹ̀lú ṣe sọ yín di ẹ̀gàn, àti ẹni àìkàsí níwájú gbogbo ènìyàn, nítorí ẹ̀yin kò tẹ̀lé ọ̀nà mi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń ṣe ojúsàájú nínú òfin.”

  4. “Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ ṣìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi Òkun.

  5. Ègbé ni fún ayé nítorí gbogbo ohun ìkọ̀sẹ̀ rẹ̀! Ohun ìkọ̀sẹ̀ kò le ṣe kó má wà, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí ìkọ̀sẹ̀ náà ti wá!