Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Metals

41 ẹsẹ · 17 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Orúkọ èkínní ni Pisoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà.

  2. (Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá àti òkúta óníkìsì oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú).

  3. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè.

  4. Nígbà náà ni kí o mú kọ́ọ̀bù idẹ mi sí ẹnu àpò èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn nínú wọn pẹ̀lú owó tí ó fi ra ọkà,” ó sì ṣe bí Josẹfu ti sọ.

  5. Ìwọ fẹ́ èémí rẹ, òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n rì bí òjé ni àárín omi ńlá.

  6. Ìwọ yóò ṣì ṣe ìwo orí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, kí àwọn ìwo náà àti pẹpẹ náà lè ṣe ọ̀kan, ìwọ yóò sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ.

  7. Ìwọ yóò sí ṣe ni wẹ́wẹ́, iṣẹ́ àwọ̀n idẹ, kí o sì ṣe òrùka idẹ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin iṣẹ́ àwọ̀n náà.

  8. Eleasari àlùfáà sì wí fún àwọn olórí ogun náà pé, “Èyí ní ìlànà òfin tí Olúwa fi lélẹ̀ ní àṣẹ fún Mose.

  9. Kìkì i wúrà, fàdákà, idẹ, irin, idẹ àti òjé.

  10. Ohunkóhun tí ó lè la iná ni kí ẹ̀yin ó mú la iná, nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n ẹ yóò fi omi ìyàsímímọ́ sọ ọ́ di mímọ́. Àti gbogbo ohun tí kò lè la iná kọjá ni kí a mú la inú omi.

  11. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fi ohun èlò irin lu ènìyàn tí ó kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa, apànìyàn náà.

  12. Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá.

  13. Nítorí náà òun dá sílífà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì mú igba ṣékélì fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà ẹni tí ó fi wọ́n rọ ère fínfín àti ère dídà. Wọ́n sì kó wọn sí ilé Mika.

  14. Ọba sì dá wọn ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani lágbedeméjì Sukkoti àti Saretani.

  15. Bẹ́ẹ̀ ni, ọba Rehoboamu dá àwọn àpáta idẹ láti fi dípò wọn, ó sì fi èyí lé àwọn alákòóso àti olùṣọ́ tí ó wà ní ẹnu iṣẹ́ ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ààfin ọba lọ́wọ́.

  16. ogún ago wúrà tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki, àti ohun èlò idẹ dáradára méjì ti ó ni iye lórí bí i wúrà.

  17. Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ, àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.

  18. Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin, bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.

  19. òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta safire, o sì ní erùpẹ̀ wúrà.

  20. Bí irin tí ń pọ́n irin mú bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.

  21. Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ, èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù, n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.

  22. Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ, dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ, àti irin dípò òkúta. Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹ àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.

  23. Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkan, kí ó lè yọ́ òjé, ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán; a kò si ya ènìyàn búburú kúrò.

  24. “Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ti di ìdàrọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, idẹ, irin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà.

  25. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti idẹ jọ sínú iná ìléru láti fi iná yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárín ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́.