Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Liberality

149 ẹsẹ · 55 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ ṣọ́ra kí èrò búburú kan má ṣe sí nínú àyà rẹ wí pé, “Ọdún keje tí í ṣe ọdún ìyọ̀ǹda gbèsè ti súnmọ́,” nípa bẹ́ẹ̀, ojú rẹ a sì burú sí arákùnrin rẹ tálákà, tí ìwọ kò sì fun ní nǹkan, o kò sì fun ní nǹkan kan. Òun a si kígbe pe Olúwa nítorí rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ.

  2. Fún un tọkàntọkàn, láìsí ìkùnsínú, nítorí èyí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, àti gbogbo ìdáwọ́lé rẹ.

  3. A kò lè fẹ́ tálákà kù ní ilẹ̀ náà ní ìgbà gbogbo, mo pàṣẹ fún un yín láti lawọ́ sí àwọn arákùnrin yín, sí àwọn tálákà àti sí àwọn aláìní, ní ilẹ̀ ẹ yín.

  4. Bí Heberu ara yín kan, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin bá ta ara rẹ̀ fún ọ, tí ó sì sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ní ọdún keje, jẹ́ kí ó di òmìnira.

  5. Nígbà tí ó bá dá a sílẹ̀ má ṣe jẹ́ kí ó lọ lọ́wọ́ òfo.

  6. Fi tọkàntọkàn fún un láti inú agbo ewúrẹ́ rẹ, ilẹ̀ ìpakà rẹ, àti ibi ìfúntí rẹ. Fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti bùkún fún ọ tó.

  7. Ẹ rántí pé ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ní Ejibiti, Olúwa Ọlọ́run yín sì rà yín padà, ìdí nìyí tí mo fi pa àṣẹ yìí fún un yín lónìí.

  8. Ṣùgbọ́n bí ìránṣẹ́ rẹ bá sọ fún ọ pé, “Èmi kò fẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,” nítorí pé ó fẹ́ràn ìwọ àti ìdílé rẹ, tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn,

  9. kí ìwọ kí ó mú ìlu kan lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn, yóò sì di ẹrú rẹ láéláé. Bẹ́ẹ̀ náà ni kí o ṣe sí ìránṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ.

  10. Má ṣe kà á sí ohun ìnira láti dá ẹrú rẹ sílẹ̀, nítorí ìsìnrú rẹ̀ fún ọ, ní ọdún mẹ́fà náà tó ìlọ́po méjì iṣẹ́ alágbàṣe, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ.

  11. Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, àní gbogbo ẹ̀yà Lefi, wọn kì yóò ní ìpín tàbí ogún láàrín Israẹli, wọn yóò máa jẹ nínú ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa, nítorí òun ni ogún un tiwọn.

  12. Wọn kì yóò ní ìní láàrín àwọn arákùnrin wọn; Olúwa ni yóò jẹ́ ìní i tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.

  13. Gbogbo èyí ni yóò jẹ́ ìpín àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó fi akọ màlúù tàbí àgùntàn rú ẹbọ; wọn yóò fi èjìká àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì àti gbogbo inú fún àlùfáà.

  14. Àkọ́so irúgbìn ọkà rẹ, ti wáìnì àti ti òróró rẹ, àti àkọ́rẹ́ irun àgùntàn rẹ ni ìwọ yóò fi fún wọn.

  15. Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n àti àwọn ọmọ wọn láti inú gbogbo ẹ̀yà láti dúró àti láti ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa títí láé.

  16. Tí ọmọ Lefi kan bá sì wá láti ibikíbi nínú àwọn ìlú u yín ní Israẹli, níbi tí ó ń gbé ṣe àtìpó, tí ó sì wá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀ sí ibi tí Olúwa yóò yàn.

  17. Nígbà náà ni ó lè máa ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi arákùnrin rẹ̀ ti ń dúró ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú Olúwa níbẹ̀.

  18. Wọn yóò ní ìpín kan láti jẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti gba owó nípa títa ogún baba rẹ̀.

  19. Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u. Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ.

  20. Nígbà tí o bá ń gun igi olifi lára àwọn igi i rẹ, má ṣe padà lọ sí ẹ̀ka náà ní ìgbà kejì. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.

  21. Nígbà tí ìwọ bá kórè èso àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.

  22. Rántí pé ìwọ ti jẹ́ àlejò ní Ejibiti. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.

  23. “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé: “ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda.

  24. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu.

  25. Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ”