Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Journey of Israel Through The Desert

759 ẹsẹ · 177 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Mose gbé tábìlì sínú àgọ́ àjọ sí ìhà àríwá àgọ́ náà lẹ́yìn aṣọ títa,

  2. ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  3. Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òdìkejì tábìlì ní ìhà gúúsù àgọ́ náà.

  4. Ó sì tan àwọn fìtílà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  5. Mose gbé pẹpẹ wúrà sínú àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa

  6. ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  7. Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà.

  8. Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  9. Ó gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀,

  10. Mose, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn.

  11. Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  12. Mose sì gbé àgbàlá tí ó yí àgọ́ náà kà ró àti pẹpẹ, ó sì ta aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà sí àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe parí iṣẹ́ náà.

  13. Nígbà náà ni àwọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo Olúwa bo àgọ́ náà.

  14. Mose kò sì lè wọ inú àgọ́ àjọ, nítorí àwọsánmọ̀ wà ní orí àgọ́, ògo Olúwa sì ti kún inú àgọ́ náà.

  15. Ní gbogbo ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli nígbàkígbà tí a bá ti fa ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sókè kúrò lórí àgọ́, wọ́n máa ń jáde lọ;

  16. ṣùgbọ́n tí àwọsánmọ̀ kò bá gòkè wọn kò ní jáde títí di ọjọ́ tí ó bá gòkè.

  17. Nítorí náà àwọsánmọ̀ Olúwa wà lórí àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọsánmọ̀ ní alẹ́, ní ojú gbogbo ilé Israẹli ní gbogbo ìrìnàjò wọn.

  18. Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé,

  19. “Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

  20. Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun.

  21. Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.

  22. “Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí: “Láti ọ̀dọ̀ Reubeni, Elisuri ọmọ Ṣedeuri.

  23. Láti ọ̀dọ̀ Simeoni, Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.

  24. Láti ọ̀dọ̀ Juda, Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.

  25. Láti ọ̀dọ̀ Isakari, Netaneli ọmọ Suari.