Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Journey of Israel Through The Desert

759 ẹsẹ · 177 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Mose foríbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ó sì sìn.

  2. Olúwa sì wí fún Mose pé, “Kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, nítorí nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Èmi bá ìwọ àti Israẹli dá májẹ̀mú.”

  3. Mose wà níbẹ̀ pẹ̀lú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru láìjẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà òfin mẹ́wàá sára wàláà.

  4. Nígbà tí Mose sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Sinai pẹ̀lú wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀, òun kò mọ̀ pé ojú òun ń dán nítorí ó bá Olúwa sọ̀rọ̀.

  5. Olúwa sì wí fún Mose pé,

  6. “Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní ni kí ó gbé àgọ́ náà, àgọ́ àjọ náà ró.

  7. Gbé àpótí ẹ̀rí sí inú rẹ̀, kí ó sì bo àpótí náà pẹ̀lú aṣọ títa.

  8. Gbé tábìlì náà wọ ilé, kí o sì to àwọn ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lé e lórí. Nígbà náà gbé ọ̀pá fìtílà wọlé, kí o sì to àwọn fìtílà rẹ̀.

  9. Gbé pẹpẹ wúrà ti tùràrí sí iwájú àpótí ẹ̀rí, kí o sì fi aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà sí ara àgọ́ náà.

  10. “Gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí iwájú ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà, àgọ́ àjọ;

  11. gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, kí o sì fi omi sí inú rẹ̀.

  12. Gbé àgbàlá ró yìí ka, kí ó sì fi aṣọ títa sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà.

  13. “Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀, yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́.

  14. Ta òróró sára pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ya pẹpẹ náà sí mímọ́, yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ.

  15. Ta òróró sára agbada náà àti ẹsẹ̀ rẹ, kí o sì yà wọ́n sí mímọ́.

  16. “Mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì wẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omi.

  17. Nígbà náà wọ Aaroni ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà.

  18. Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n.

  19. Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ní orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.”

  20. Mose ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

  21. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ní ọdún kejì.

  22. Nígbà tí Mose gbé àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró.

  23. Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

  24. Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ.

  25. Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.