Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Jerusalem: Water supply brought in from the Gihon by Hezekiah

8 ẹsẹ · 117 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Water supply brought in from the Gihon by Hezekiah

  1. Ó gbèrò pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ láti di orísun omi ní ìta ìlú ńlá, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.

  2. Ọ̀pọ̀ ogun ọkùnrin péjọ, wọ́n sì dí gbogbo àwọn orísun àti àwọn omi tó ń sàn tí ó ń sàn gba ti ilẹ̀ náà. “Kí ni ó dé tí àwọn ọba Asiria fi wá tí wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ omi?” Wọ́n wí.

  3. Ní òru, mo jáde lọ sí àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jakali àti sí ẹnu ibodè Ààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó odi Jerusalẹmu tí ó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun.

  4. Nígbà náà ni mo lọ sí ẹnu ibodè orísun àti sí adágún omi ọba, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tó fún ẹranko mi láti kọjá;

  5. bẹ́ẹ̀ ni mo gòkè àfonífojì ní òru, mo ń wo odi. Ní ìparí, mo padà sẹ́yìn, mo sì tún wọlé láti ibodè àfonífojì.

  6. Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀, ìwọ ti tọ́jú omi sínú adágún ti ìsàlẹ̀.

  7. Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu ó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ògiri lágbára.

  8. Ìwọ mọ agbemi sí àárín ògiri méjì fún omi inú adágún àtijọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀ tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ó gbèrò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.