Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Jerusalem: Taken and plundered by Shishak

4 ẹsẹ · 117 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Taken and plundered by Shishak

  1. Lẹ́yìn ìgbà tí a fi ìjọba Rehoboamu múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba, tí ó sì ti di alágbára, òun àti gbogbo Israẹli, pẹ̀lú rẹ̀ ni wọ́n pa òfin Olúwa tì.

  2. Nítorí tí wọn kò ṣọ òtítọ́ sí Olúwa. Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu ní ọdún karùn-ún ti ọba Rehoboamu.

  3. Pẹ̀lú ẹgbàá mẹ́fà (12,000) kẹ̀kẹ́ àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta (60,000) àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin àti àìníye ọ̀wọ́ ogun ti Libia, Sukki àti Kuṣi, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti Ejibiti.

  4. Ó fi agbára mú àwọn ìlú ààbò ti Juda, pẹ̀lú wá sí Jerusalẹmu bí ó ti jìnnà tó.