Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Jerusalem: Confederated kings defeated, and the king of Jerusalem slain by Joshua

12 ẹsẹ · 117 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Confederated kings defeated, and the king of Jerusalem slain by Joshua

  1. Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli padà sí ibùdó ní Gilgali.

  2. Ní báyìí àwọn ọba Amori márùn-ún ti sálọ, wọ́n sì fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta kan ní Makkeda,

  3. nígbà tí wọ́n sọ fún Joṣua pé, a ti rí àwọn ọba márààrún, ti ó fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta ní Makkeda,

  4. ó sì wí pé, “Ẹ yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò àpáta náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin sí ibẹ̀ láti ṣọ́ ọ.

  5. Ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe dúró! Ẹ lépa àwọn ọ̀tá yín, ẹ kọlù wọ́n láti ẹ̀yìn, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó dé ìlú wọn, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín tí fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”

  6. Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ-ogun àwọn ọba márààrún run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn.

  7. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní ibùdó ogun ní Makkeda ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Israẹli.

  8. Joṣua sì wí pe, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba márààrún jáde wá fún mi.”

  9. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúrò nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni.

  10. Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọba náà tọ Joṣua wá, ó pe gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli, ó sì sọ fún àwọn olórí ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ bí, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín lé ọrùn àwọn ọba wọ̀nyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wá sí iwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ lé ọrùn wọn.

  11. Joṣua sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni Olúwa yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.”

  12. Nígbà náà ni Joṣua kọlù wọ́n, ó sì pa àwọn ọba márààrún náà, ó sì so wọ́n rọ̀ ní orí igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí orí igi títí di ìrọ̀lẹ́.