Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Emulation: General references

13 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

  1. Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedonia.

  2. Bí ó ti jẹ́ pé a dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti àìlódiwọ̀n àìní wọn ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn.

  3. Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn.

  4. Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́.

  5. Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnra wọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run.

  6. Tó bẹ́ẹ̀ tí àwa fi gba Titu níyànjú pé, bí ó tí bẹ̀rẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì parí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí nínú yín pẹ̀lú.

  7. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti pọ̀ lóhùn gbogbo, ní ìgbàgbọ́, àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀, àti nínú iṣẹ́ ìyìnrere gbogbo, àti ní ìfẹ́ yín sí wa, ẹ rí i wí pé ẹ̀yin pọ̀ sí i nínú ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí pẹ̀lú.

  8. Kì í ṣe nípa àṣẹ ni mo fi ń sọ ọ́, ṣùgbọ́n kí a lè rí ìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín pẹ̀lú, nípa iṣẹ́ ìyìnrere ẹlòmíràn.

  9. Nísinsin yìí, nípa ti ìpín fún ni fún àwọn ènìyàn mímọ́, kò tún yẹ mọ́ fún mi láti kọ̀wé sí yin ju bẹ́ẹ̀ lọ.

  10. Nítorí mo mọ ìtara láti ṣe ìrànlọ́wọ́ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedonia nítorí yín, pé, àwọn ara Akaia ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè.

  11. Ṣùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí; pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀.

  12. Kí ó má ba à jẹ́ pé, bí àwọn nínú ara Makedonia bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúra sílẹ̀, ojú a sì tì wá kì í ṣe ẹ̀yin, ní ti ìgbẹ́kẹ̀lé yìí.

  13. Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ́bi ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti a fi ìkùnsínú ṣe.