Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Doubting: General references

31 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kíyèsi i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn, ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le.

  2. Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró, ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera.

  3. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọlù ọ́; ara rẹ kò lélẹ̀.

  4. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ?

  5. Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn, èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.

  6. Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá, ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí.

  7. Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi, ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.

  8. Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó! Alágbára ni, tàbí ní ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò?

  9. Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi yóò dá mi lẹ́bi; bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.

  10. “Olóòótọ́ ni mo ṣe, síbẹ̀ èmi kò kíyèsi ara mi, ayé mi ní èmi ìbá máa gàn.

  11. Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi ṣe sọ: ‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’

  12. Bí ìjàǹbá bá pa ni lójijì, yóò rẹ́rìn-ín nínú ìdààmú aláìṣẹ̀.

  13. Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀; nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.

  14. Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà, Olódùmarè sì ń dààmú mi.

  15. Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.

  16. “Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn; èmi dìde dúró ìwọ sì wò mí lásán.

  17. Ìwọ padà di ẹni ìkà sí mi; ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ fi dè mí ní ọ̀nà.

  18. Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi? Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi? Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run, nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín, Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

  19. Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi: nítorí náà, èmi ó rántí rẹ láti ilẹ̀ Jordani wá, láti Hermoni láti òkè Mibsari.

  20. Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́; nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.

  21. Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu; a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.

  22. Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,” èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.

  23. Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, Ó jẹ́ ìnilára fún mi,

  24. títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.

  25. “Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé? Ki yóò ha ṣe ojúrere rẹ̀ mọ́?