- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Babylon
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Lọ, kí o bojúwòde kí o sì wá sọ ohun tí ó rí.
Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin, àwọn tó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àwọn tí ó gun ìbákasẹ, jẹ́ kí ó múra sílẹ̀, àní ìmúra gidigidi.”
Òun sì kígbe pé, kìnnìún kan, “Láti ọjọ́ dé ọjọ́, olúwa mi, mo dúró lórí ilé ìṣọ́ ní ọ̀sán, a sì fi mí ìṣọ́ mi ní gbogbo òru.
Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀ wá yìí nínú kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin. Ó sì mú ìdáhùn padà wá: ‘Babeli ti ṣubú, ó ti ṣubú! Gbogbo àwọn ère òrìṣà rẹ̀ ló fọ́nká sórí ilẹ̀!’ ”
Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gún mọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà, mo sọ ohun tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Israẹli.
“Sọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku, wúńdíá ọmọbìnrin Babeli; jókòó ní ilẹ̀ láìsí ìtẹ́, ọmọbìnrin àwọn ará Babeli. A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́.
Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun; mú ìbòjú rẹ kúrò. Ká aṣọ ẹsẹ̀ rẹ sókè, ká aṣọ itan, kí o sì la odò wọ̀n-ọn-nì kọjá.
Ìhòhò rẹ ni a ó sí síta àti ìtìjú rẹ ni a ó ṣí sílẹ̀. Èmi yóò sì gba ẹ̀san, Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”
Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ òun ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
“Jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn, ọmọbìnrin àwọn ará Babeli; a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrin àwọn ilẹ̀ ọba mọ́.
Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mi tí mo sì ba ogún mi jẹ́, mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n. Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lú ní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.
Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀síwájú títí láé— ọbabìnrin ayérayé!’ Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi nǹkan wọ̀nyí tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.
“Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi kì yóò di opó tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’
Méjèèjì yìí ni yóò wá sórí rẹ láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà: pípàdánù ọmọ àti dídi opó. Wọn yóò wá sórí rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ àti àwọn èpè rẹ tí ko lágbára.
Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ ó sì ti wí pé, ‘Kò sí ẹni tí ó rí mi?’ Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà nígbà tí o wí fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’
Ìparun yóò dé bá ọ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò. Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́ tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò; òfò kan tí o kò le faradà ni yóò wá lójijì sí oríì rẹ.
“Tẹ̀síwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹ àti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo, tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá. Bóyá o le è ṣàṣeyọrí, bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.
Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀! Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú, àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ láti oṣù dé oṣù, jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.
Lóòótọ́ wọ́n dàbí ìṣẹ́pẹ́ igi; iná ni yóò jó wọn dànù. Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là lọ́wọ́ agbára iná náà. Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná níhìn-ín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.
Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìí gbogbo èyí ní o tí ṣíṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀ tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀; kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Juda lé ọba Babeli lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Babeli tàbí kí ó pa wọ́n.
Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀tá wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá ọba Juda. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Babeli.
Àti ìwọ Paṣuri, gbogbo ènìyàn inú ilé rẹ yóò sì lọ ṣe àtìpó ní Babeli. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, tí wọn yóò sì sin ọ́ síbẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ìwọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.”
Ṣùgbọ́n Jeremiah dáhùn wí pé, “Sọ fún Sedekiah,
‘Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí, Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá ọba àti àwọn ará Babeli tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí.