Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Babylon: Grief of the Jews in

6 ẹsẹ · 73 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Grief of the Jews in

  1. Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.

  2. Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò, tí ó wà láàrín rẹ̀.

  3. Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa, àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá; wọn wí pé, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa!”

  4. Àwa ó ti ṣe kọ orin Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì

  5. Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.

  6. Bí èmi kò bá rántí rẹ, jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi; bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú olórí ayọ̀ mi gbogbo.