Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Babylon: Captivity of the Jews by

13 ẹsẹ · 73 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Captivity of the Jews by

  1. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Juda lé ọba Babeli lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Babeli tàbí kí ó pa wọ́n.

  2. Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀tá wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá ọba Juda. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Babeli.

  3. Àti ìwọ Paṣuri, gbogbo ènìyàn inú ilé rẹ yóò sì lọ ṣe àtìpó ní Babeli. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, tí wọn yóò sì sin ọ́ síbẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ìwọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.”

  4. “Gòkè lọ sí Lebanoni, kígbe síta, kí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Baṣani, kí o kígbe sókè láti Abarimu, nítorí a ti ṣẹ́ gbogbo olùfẹ́ rẹ túútúú.

  5. Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu, ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’ Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ, ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́.

  6. Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ, gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbèkùn, nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́ nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ.

  7. Ìwọ tí ń gbé ‘Lebanoni,’ tí ó tẹ́ ìtẹ́ sí orí igi kedari, ìwọ yóò ti kérora pẹ́ tó, nígbà tí ìrora bá dé bá ọ, ìrora bí i ti obìnrin tí ń rọbí!

  8. “Dájúdájú bí èmi ti wà láààyè,” ni Olúwa wí, “Bí Koniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀.

  9. Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadnessari, ọba Babeli àti ọwọ́ àwọn ará Babeli.

  10. Èmi ó fi ìwọ àti ìyá tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn, níbi tí a kò bí ẹnikẹ́ni nínú yín sí. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì yóò kú sí.

  11. Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli,” ni Olúwa wí. “Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè àyíká rẹ̀. Èmi yóò pa wọ́n run pátápátá, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé.

  12. Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà.

  13. Gbogbo orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì sìn ọba Babeli ní àádọ́rin ọdún.