Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Matiu 13:6nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọn sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò.

  2. Matiu 13:7nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárín ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa.

  3. Matiu 13:8nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́rùn-ún, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ti ó gbìn.

  4. Matiu 13:9nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́.”

  5. Matiu 13:10nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bí i pé, “Èéṣe tí ìwọ ń fi òwe bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀?”

  6. Matiu 13:11nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì da wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a ti fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wọn.

  7. Matiu 13:12nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ẹnikẹ́ni tí ó ní, òun ni a ó fún sí i, yóò sì ní lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ ẹni tí kò ní, ni a ó ti gbà èyí kékeré tí ó ní náà.

  8. Matiu 13:13nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ìdí nìyìí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀: “Ní ti rí rí, wọn kò rí; ní ti gbígbọ́ wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yé wọn.

  9. Matiu 13:14nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Sí ara wọn ni a ti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Isaiah ṣẹ: “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọ́n kì yóò sì yé yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye.

  10. Matiu 13:15nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́ etí wọn sì wúwo láti gbọ́ ojú wọn ni wọ́n sì dì nítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn rí kí wọ́n má ba à fi etí wọn gbọ́ kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òye, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi ba à le mú wọn láradá.’

  11. Matiu 13:16nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ojú yín, nítorí wọ́n ríran, àti fún etí yín, nítorí ti wọ́n gbọ́.

  12. Matiu 13:17nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti ènìyàn Ọlọ́run ti fẹ́ rí ohun tí ẹ̀yin ti rí, ki wọ́n sì gbọ́ ohun tí ẹ ti gbọ́, ṣùgbọ́n kò ṣe é ṣe fún wọn.

  13. Matiu 13:18nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    “Nítorí náà, ẹ fi etí sí ohun tí òwe afúnrúgbìn túmọ̀ sí,

  14. Matiu 13:19nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    nígbà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìjọba ọ̀run ṣùgbọ́n tí kò yé e, lẹ́yìn náà èṣù á wá, a sì gba èyí tí a fún sí ọkàn rẹ̀ kúrò. Èyí ni irúgbìn ti a fún sí ẹ̀bá ọ̀nà.

  15. Matiu 13:20nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ó sì gba irúgbìn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ orí àpáta, ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, lọ́gán, ó sì fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà.

  16. Matiu 13:21nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nítorí kò ní gbòǹgbò, ó wà fún ìgbà díẹ̀; nígbà tí wàhálà àti inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà ní ojú kan náà yóò sì kọsẹ̀.

  17. Matiu 13:22nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso nínú rẹ̀.

  18. Matiu 13:23nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e; òun sì so èso òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n.”

  19. Matiu 13:24nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Jesu tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí àgbẹ̀ kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀,

  20. Matiu 13:25nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    ṣùgbọ́n ní òru ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá sí oko náà ó sì gbin èpò sáàrín alikama, ó sì bá tirẹ̀ lọ.

  21. Matiu 13:26nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí alikama náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, tí ó sì so èso, nígbà náà ni èpò náà fi ara hàn.

  22. Matiu 13:27nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àgbẹ̀ náà wá, wọ́n sọ fún un pé, ‘Ọ̀gá, irúgbìn rere kọ́ ni ìwọ ha gbìn sí oko rẹ nì? Báwo ni èpò ṣe wà níbẹ̀ nígbà náà?’

  23. Matiu 13:28nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    “Ó sọ fún wọn pé, ‘Ọ̀tá ni ó ṣe èyí.’ “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tún bí i pé, ‘Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ kí a fa èpò náà tu kúrò?’

  24. Matiu 13:29nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    “Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá, nítorí bí ẹ̀yin bá ń tu èpò kúrò, ẹ ó tu alikama dànù pẹ̀lú rẹ̀.

  25. Matiu 13:30nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì máa dàgbà pọ̀, títí di àsìkò ìkórè. Èmi yóò sọ fún àwọn olùkórè náà láti kọ́kọ́ ṣa àwọn èpò kúrò kí wọ́n sì dìwọ́n ní ìtí, kí a sì sun wọn, kí wọ́n sì kó alikama sínú àká mi.’ ”