Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Johanu 5:10nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà àwọn Júù wí fún ọkùnrin náà tí a mú láradá pé, “Ọjọ́ ìsinmi ni òní; kò tọ́ fún ọ láti gbé àkéte rẹ.”

  2. Johanu 5:11nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹni tí ó mú mi láradá, ni ó wí fún mi pé, ‘Gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.’ ”

  3. Johanu 5:12nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni wọ́n bi í lérè wí pé, “Ọkùnrin wo ni ẹni tí ó wí fún ọ pé gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?”

  4. Johanu 5:13nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí a mú láradá náà kò sì mọ̀ ẹni tí ó jẹ́ nítorí Jesu ti kúrò níbẹ̀, àwọn ènìyàn púpọ̀ wà níbẹ̀.

  5. Johanu 5:14nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn náà, Jesu rí i nínú tẹmpili ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!”

  6. Johanu 5:15nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé, Jesu ni ẹni tí ó mú òun láradá.

  7. Johanu 5:16nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jesu, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí o ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi.

  8. Johanu 5:17nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”

  9. Johanu 5:18nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí èyí ni àwọn Júù túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, kì í ṣe nítorí pé ó ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó wí pẹ̀lú pé, Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó ń mú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba.

  10. Johanu 5:19nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe, nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú.

  11. Johanu 5:20nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí Baba fẹ́ràn ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án, òun yóò sì fi iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín.

  12. Johanu 5:21nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di alààyè: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di alààyè pẹ̀lú.

  13. Johanu 5:22nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́,

  14. Johanu 5:23nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an.

  15. Johanu 5:24nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun, òun kì yóò sì wá sí ìdájọ́; ṣùgbọ́n ó ti ré ikú kọjá bọ́ sí ìyè.

  16. Johanu 5:25nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọ́run, àwọn tí ó bá gbọ́ yóò sì yè.

  17. Johanu 5:26nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó sì fi fún ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀;

  18. Johanu 5:27nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì fún un ní àṣẹ láti máa ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú, nítorí tí òun jẹ́ Ọmọ Ènìyàn.

  19. Johanu 5:28nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    “Kí èyí má ṣe yà yín lẹ́nu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní ibojì yóò gbọ́ ohun rẹ̀.

  20. Johanu 5:29nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Wọn ó sì jáde wá; àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè; àwọn tí ó sì ṣe búburú sí àjíǹde ìdájọ́.

  21. Johanu 5:30nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Èmi kò le ṣe ohun kan fún ara mi, bí mo ti ń gbọ́ ni, mo ń dájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí èmi kò wá ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.

  22. Johanu 5:31nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    “Bí èmi bá ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òtítọ́.

  23. Johanu 5:32nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ẹlòmíràn ni ẹni tí ń jẹ́rìí mi; èmi sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi tí ó jẹ́.

  24. Johanu 5:33nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    “Ẹ̀yin ti ránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Johanu, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́.

  25. Johanu 5:34nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n èmi kò gba ẹ̀rí lọ́dọ̀ ènìyàn, nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là.