- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Daniẹli 3:4nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni a kéde kígbe sókè wí pé, “Ohun tí a paláṣẹ fún un yín láti ṣe nìyìí, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo.
- Daniẹli 3:5nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Bí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò, kí ẹ wólẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀.
- Daniẹli 3:6nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ tí kò bá wólẹ̀, kí ó fi orí balẹ̀, kí a ju ẹni náà sínú iná ìléru.”
- Daniẹli 3:7nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè, àti èdè gbogbo wólẹ̀, wọ́n sì fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀.
- Daniẹli 3:8nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Ní àsìkò yìí ni àwọn awòràwọ̀ bọ́ síwájú, wọ́n sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ará Juda.
- Daniẹli 3:9nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Wọ́n sọ fún ọba Nebukadnessari pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.
- Daniẹli 3:10nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Ìwọ ọba ti pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin gbọdọ̀ wólẹ̀ kí ó fi orí balẹ̀ fún ère wúrà
- Daniẹli 3:11nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
àti ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó foríbalẹ̀, a ó sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú iná ìléru.
- Daniẹli 3:12nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n àwọn ará Juda kan wà, àwọn tí a yàn láti ṣe olórí agbègbè ìjọba Babeli: Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, wọ́n ò ka ìwọ ọba sí. Wọn kò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”
- Daniẹli 3:13nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Nebukadnessari pàṣẹ ní ìrunú àti ìbínú pé kí a mú Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wá, wọ́n sì mú wọn wá síwájú ọba.
- Daniẹli 3:14nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Nebukadnessari wí fún wọn wí pé, “Ṣé òtítọ́ ni, Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wí pé ẹ̀yin kò sin òrìṣà mi àti pé ẹ̀yin kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí èmi gbé kalẹ̀.
- Daniẹli 3:15nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Ní ìsinsin yìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetán láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru. Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”
- Daniẹli 3:16nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego dá ọba lóhùn wí pé, “Nebukadnessari, kì í ṣe fún wa láti gba ara wa sílẹ̀ níwájú u rẹ nítorí ọ̀rọ̀ yìí.
- Daniẹli 3:17nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba.
- Daniẹli 3:18nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ dájú wí pé àwa kò ní sin òrìṣà rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”
- Daniẹli 3:19nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Nebukadnessari bínú gidigidi sí Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ojú u rẹ̀ sì yípadà, ó sì pàṣẹ pé, kí wọn dá iná ìléru náà kí ó gbóná ní ìlọ́po méje ju èyí tí wọn ń dá tẹ́lẹ̀,
- Daniẹli 3:20nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
ó sì pàṣẹ fún àwọn alágbára nínú ogun rẹ̀ pé, kí wọ́n de Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, kí wọn sì jù wọ́n sínú iná ìléru.
- Daniẹli 3:21nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni a dè wọ́n pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn, ṣòkòtò, ìbòrí àti àwọn aṣọ mìíràn, a sì jù wọ́n sínú iná ìléru.
- Daniẹli 3:22nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Nítorí bí àṣẹ ọba ṣe le tó, tí iná ìléru náà sì gbóná, ọwọ́ iná pa àwọn ọmọ-ogun tí wọ́n mú Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego lọ.
- Daniẹli 3:23nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ṣubú lulẹ̀ sínú iná ìléru náà pẹ̀lú bí a ṣe dè wọ́n.
- Daniẹli 3:24nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ó ya Nebukadnessari ọba lẹ́nu, ó sì yára dìde dúró, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ pé, “Ṣe bí àwọn mẹ́ta ni a gbé jù sínú iná?” Wọ́n wí pé, “Òtítọ́ ni ọba.”
- Daniẹli 3:25nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Ó sì wí pé, “Wò ó! Mo rí àwọn mẹ́rin tí a kò dè tí wọ́n ń rìn ká nínú iná, ẹni kẹrin dàbí ọmọ ọlọ́run.”
- Daniẹli 3:26nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, ni Nebukadnessari dé ẹnu-ọ̀nà iná ìléru, ó sì kígbe pé, “Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹ jáde, ẹ wá níbi!” Nígbà náà ni Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego jáde láti inú iná.
- Daniẹli 3:27nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ-aládé, ìjòyè, baálẹ̀, àwọn ìgbìmọ̀ ọba péjọ sí ọ̀dọ̀ ọ wọn. Wọ́n rí i wí pé iná kò ní agbára lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò jó wọn lára, bẹ́ẹ̀ ni irun orí wọn kò jóná, àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn kò jóná, òórùn iná kò rùn ní ara wọn rárá.
- Daniẹli 3:28nǹkan bí 580 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, ni Nebukadnessari sọ wí pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ẹni tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àṣẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn.