- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Esekiẹli 33:6nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n bí alóre bá rí idà tí o ń bọ̀, tí kò sì fọn ìpè láti ki àwọn ènìyàn nílọ̀, tí idà náà wá, tí ó sì gba ẹ̀mí ọ̀kan nínú wọn, a yóò mú ọkùnrin náà lọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n èmi yóò béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.’
- Esekiẹli 33:7nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“Ọmọ ènìyàn, èmi fi ọ ṣe alóre fún ilé Israẹli; nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, kí o sì fún wọn ni ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.
- Esekiẹli 33:8nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Nígbà ti mo bá sọ fún ẹni búburú pé, ‘A! Ẹni búburú, ìwọ yóò kú dandan,’ ti ìwọ kò sì sọ̀rọ̀ síta láti yí i lọ́kàn padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ẹni búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èmi yóò sì béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ.
- Esekiẹli 33:9nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kìlọ̀ fún ẹni búburú láti yí padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, tí òun kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, òun yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ti gba ọkàn rẹ̀ là.
- Esekiẹli 33:10nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“Ọmọ ènìyàn; sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí yìí ní ìwọ sọ: “Àwọn ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ wa tẹ orí wa ba, àwa sì ń ṣòfò dànù nítorí wọn. Bá wó wa ni a ṣe lè yè?” ’
- Esekiẹli 33:11nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Sọ fún wọn pé, ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè ni Olúwa Olódùmarè wí, èmi kò ní inú dídùn sí ikú ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, kí wọ̀nyí padà kúrò ní ọ̀nà wọn gbogbo kì wọn kì ó sì yè. Yí! Yípadà kúrò ni ọ̀nà búburú gbogbo! Kí ló dé tí ìwọ yóò kú ẹ̀yin ènìyàn Israẹli?’
- Esekiẹli 33:12nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ, ‘Ìṣòdodo ti olódodo ènìyàn kì yóò gbà á nígbà tí òun bá ṣe àìgbọ́ràn, ìwà búburú ènìyàn búburú kì yóò mú kí o ṣubú nígbà tí ó bá yí padà kúrò nínú rẹ̀. Bí olódodo ènìyàn bá ṣẹ̀, a kò ni jẹ́ kí ó yè nítorí òdodo rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀.’
- Esekiẹli 33:13nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Bí mo bá sọ fún olódodo ènìyàn pé òun yóò yè, ṣùgbọ́n nígbà náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ̀ tí ó sì ṣe búburú, a kò ní rántí nǹkan kan nínú iṣẹ́ òdodo tí o ti ṣe sẹ́yìn; òun yóò kú nítorí búburú tí ó ṣe.
- Esekiẹli 33:14nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, ‘Ìwọ yóò kú dandan,’ ṣùgbọ́n tí ó bá yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ti o sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí o yẹ.
- Esekiẹli 33:15nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Tí ó bá mu ògo padà, tí o sì da ohun tí o ti jí gbé padà, tí ó sì tẹ̀lé òfin tí ó ń fún ni ní ìyè, tí kò sì ṣe búburú, òun yóò yè dandan; òun kì yóò kú.
- Esekiẹli 33:16nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
A kò ní rántí ọ̀kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá. Ó ti ṣe èyí tí ó tọ àti èyí tí o yẹ; òun yóò sì yè dájúdájú.
- Esekiẹli 33:17nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“Síbẹ̀ àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ sọ pé, ‘Ọ̀nà Olúwa kò tọ́.’ Ṣùgbọ́n ọ̀nà tí àwọn ní ó tọ́.
- Esekiẹli 33:18nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Bí olódodo ènìyàn ba yípadà kúrò nínú òdodo rẹ̀, tí o sì ṣe búburú, òun yóò kú nítorí rẹ̀.
- Esekiẹli 33:19nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú búburú rẹ̀, tí ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ, òun yóò yè nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀.
- Esekiẹli 33:20nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Síbẹ̀, ilé Israẹli ìwọ wí pé, ‘Ọ̀nà Olúwa ki i ṣe òtítọ́.’ Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ ṣe rí.”
- Esekiẹli 33:21nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹwàá, ọdún kejìlá ìkólọ wa, ọkùnrin kan tí ó sá kúrò ni Jerusalẹmu wá sọ́dọ̀ mi, ó sì wí pé, “Ìlú ńlá náà ti ṣubú!”
- Esekiẹli 33:22nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ku ọ̀la tí ẹni tí ó sálọ náà yóò dé, ọwọ́ Olúwa sì níbẹ̀ lára mi, o sì ya ẹnu mi ki ọkùnrin náà tó wá sọ́dọ̀ mi ní òwúrọ̀. Ẹnu mí sì ṣí, èmi kò sì yadi mọ́.
- Esekiẹli 33:23nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
- Esekiẹli 33:24nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“Ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn tí ó ń gbé nínú ìparun ní ilẹ̀ Israẹli ń wí pé, ‘Abrahamu jẹ́ ọkùnrin kan, síbẹ̀ o gba ilẹ̀ ìní náà. Ṣùgbọ́n àwa pọ̀, lóòótọ́ a ti fi ilẹ̀ náà fún wa gẹ́gẹ́ bí ìní wa.’
- Esekiẹli 33:25nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Níwọ́n ìgbà tí ẹ̀yin jẹ ẹran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ni inú rẹ̀, tí ẹ̀yin sì wó àwọn ère yín, tí ẹ sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà?
- Esekiẹli 33:26nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé idà yín, ẹ̀yin ṣe nǹkan ìríra, ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú yín ba á obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́. Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà?’
- Esekiẹli 33:27nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“Sọ èyí fún wọn: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Bí mo ti wà láààyè, àwọn tí ó kúrò nínú ìparun yóò ti ipa idà ṣubú, àwọn tí ẹranko búburú yóò pajẹ, àwọn tí ó sì wà ní ilé ìṣọ́ àti inú ihò òkúta ni àjàkálẹ̀-ààrùn yóò pa.
- Esekiẹli 33:28nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Èmi yóò mú kí ilẹ̀ náà di ahoro, ọ̀ṣọ́ ńlá agbára rẹ̀ kì yóò sí mọ́, àwọn òkè Israẹli yóò sì di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò ní le là á kọjá.
- Esekiẹli 33:29nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá mú ilẹ̀ náà di ahoro nítorí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ti ṣe.’
- Esekiẹli 33:30nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“Ní tìrẹ, ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn ìlú n sọ̀rọ̀ nípa rẹ ní ẹ̀gbẹ́ ògiri àti ní ẹnu-ọ̀nà ilé wọn, wọ́n ń sọ sí ara wọn wí pé, ‘Ẹ wá gbọ́ iṣẹ́ ti a ran láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá.’