Fò sí àkóónú

Zion

139 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Sion

31.7700, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Zion

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa pinnu láti fa ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Sioni ya. Ó gbé wọn sórí òsùwọ̀n, kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn. Ó mú kí ilé ìṣọ́ àti odi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀ wọ́n ṣòfò papọ̀.

  2. Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sioni jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́; wọ́n da eruku sí orí wọn wọ́n sì wọ aṣọ àkísà. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmu ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.

  3. Kí ni mo le sọ fún ọ? Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu? Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé, kí n lè tù ọ́ nínú, ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni? Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun. Ta ni yóò wò ọ́ sàn?

  4. Ọkàn àwọn ènìyàn kígbe jáde sí Olúwa. Odi ọmọbìnrin Sioni, jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò ní ọ̀sán àti òru; má ṣe fi ara rẹ fún ìtura, ojú rẹ fún ìsinmi.

  5. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Sioni tí ó ṣe iyebíye, tí wọ́n fi wúrà dídára ṣe wá dàbí ìkòkò amọ̀ lásán iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!

  6. Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀; ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde. Ó da iná ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

  7. Ìwọ ọmọbìnrin Sioni, ìjìyà rẹ yóò dópin; kò ní mú ìgbèkùn rẹ pẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Edomu, yóò jẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ní yà yóò sì fi àìṣedéédéé rẹ hàn kedere.

  8. Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni, àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda.

  9. Ẹ fun ìpè ní Sioni, ẹ sì fún ìpè ìdágìrì ní òkè mímọ́ mi. Jẹ́ kí àwọn ará ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí tí ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá, nítorí ó kù sí dẹ̀dẹ̀.

  10. Ẹ fún ìpè ní Sioni, ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú.

  11. Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni, ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́, Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín, àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.

  12. Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá; àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì. Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀, àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.

  13. “Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi. Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́; àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́.

  14. Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tí ì wẹ̀nù.

  15. Ó wí pé, “Olúwa yóò bú jáde láti Sioni, ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jerusalẹmu wá; ibùgbé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀, orí òkè Karmeli yóò sì rọ.”

  16. Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá.

  17. Ìwọ olùgbé Lakiṣi, dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára. Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin Sioni, nítorí a rí àìṣedéédéé Israẹli nínú rẹ̀.

  18. tí ó kọ́ Sioni pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀, àti Jerusalẹmu pẹ̀lú ìwà búburú.

  19. Nítorí náà, nítorí tiyín, ni a ó ṣe ro Sioni bí oko, Jerusalẹmu yóò sì di ebè àti òkè tẹmpili bí i ibi gíga igbó.

  20. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu. Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.

  21. Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn, odi alágbára ọmọbìnrin Sioni, a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín; ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”

  22. Máa yí síyìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora, ìwọ obìnrin Sioni, bí ẹni tí ń rọbí, nítorí nísinsin yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú, ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó. Ìwọ yóò lọ sí Babeli; níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà. Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.

  23. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́, ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Sioni!”

  24. “Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni, nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin, èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹ ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá.” Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwa àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé.

  25. Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, kígbe sókè, ìwọ Israẹli! Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.